Sudan Protest: Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò kọlu àwọn tó n ṣe ìwọ́de ní Sudan

Ija Sudan Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ija Sudan

Awọn ikọ alaabo l'orilẹede Sudan fi tipa-tipa wọ aarin awọn to n ṣe iwọde ifẹhonuhan ni ilu Khartoum to jẹ olu ilu orilẹeede naa ni owurọ kutu-kutu ọjọ Aje.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun ileeṣẹ amohunmaworan Arab television pe niṣe ni awọn oṣiṣẹ alaabo ọhun bẹrẹ si ni yin ibọn, ti awọn afẹhonuhan naa si n sọ pe ọna lati da iwọde ti wọn n ṣe ni ita ileeṣẹ ijọba to wa fun eto aabo ru ni.

Iroyin sọ pe eniyan kan ti padanu ẹmi rẹ, ti ọpọ eniyan si tun farapa.

Lati igba ti awọn ologun ti gbajọba lọwọ Aarẹ Omar al-Bashir ninu oṣu Kẹrin ni awọn ọmọ ogun ti n ṣe iṣakoso orilẹede naa.

Ọgbọn ọdun ni Aarẹ al-Bashir ti lo ni iṣakoso, ki awọn ọmọ ogun to o gba ijọba lọwọ rẹ.

Awọn afẹhonuhan si n sẹ iwọde ni gbogbo igba pe ki ijọba alagbada pada sori aga iṣakoso.

Ẹgbẹ to n ṣiwaju ifẹhonuhan naa sọ ninu atẹjade kan pe ''ipenija ati wahala nla ni awọn afẹhonuhan to wa niwaju olu ileeṣẹ ologun n koju, nitori bi awọn ologun ṣe n gbiyanju lati le wọn kuro." Ẹgbẹ naa n fẹ ki awọn eniyan orilẹede Sudan dide fun iranlọwọ wọn.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, to jẹ ọjọ maarun ṣaaju ki awọn ologun to gbajọba ni awọn to n fi ẹhonu han ti wa niwaju olu ileeṣẹ ologun.

Related Topics