Obasanjo - Ó dára bí Aisha ṣe ń gbarata lórí ètò áábó tó mẹ́hẹ

Aisha ati ọkọ rẹ, Muhammadu Buhari n tẹ sọrọ Image copyright @AsoRock

Aarẹ ana ni Naijiria, Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ti kesi aya aarẹ Muhammadu Buhari, Aisha, lati pe ọkọ rẹ wọ yara, ko si ba sọ ootọ ọrọ nipa eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria, pẹlu awọn ipenija miran lọkanojọkan ti a n fara gba.

Bakan naa ni Ọbasanjọ tun faramọ ọpọ koko ọrọ ti aya aarẹ n mẹnuba ninu awọn igbe gbajare to n ke pe, eto aabo Naijiria ko yanranti to , to si rọ Aisha Buhari pe ko pe ọkọ rẹ tẹ lori awọn ọrọ naa.

Ọbasanjọ gbe imọran yii kalẹ ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Kẹhinde Akinyẹmi fisita, eyi to ni o waye lasiko ti Ọbasanjọ n gbalejo awọn ọmọ igbimọ oludari feto iroyin ori ayelujara nibudo iyawe kawe rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa fikun pe, Ọbasanjọ ni oun fara mọ igbe ti Aisha n mu bọnu lasiko yii, ti nkan ko fara rọ lẹka eto aabo wa nitori bi ara ile ba n jẹ kokoro buruku, bi a ko ba tete kigbe sita, huru-hẹrẹ rẹ ko ni jẹ ka sun lori.

Ọbasanjọ wa se kare, obinrin bii ọkunrin ni ọ si aya aarẹ, fun bi ko se bu ẹẹkẹ diwọ lasiko yii ti ara ko rọ okun, ti ko si rọ adiẹ lẹka eto aabo wa lorilẹede Naijiria.

Image copyright Olusegun Obasanjo

"O yẹ ka da silẹ, ka tun ṣa ni lasiko yii, ka lee wa ojutu sawọn isoro to n mi ẹka eto aabo Naijira logbo-logbo, o si yẹ ka ba ara wa sọ ootọ ọrọ lori rẹ, lai fi epo bọyọ. Aya aarẹ ṣe daada pẹlu bo se n kigbe sita yii, sugbọn o tun ku, nibọn n ro. O yẹ ko pe ọkọ rẹ tẹ si yara ni, lati baa jiroro lori aifaraọ eto aabo naa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters

Bakan naa ni aarẹ tẹlẹ naa tun gbe imọran kalẹ pe o yẹ ki alekun eto ilanilọyẹ wa, ki awọn ọmọ Naijiria lee ni iyipada rere ti wọn n fi oju sọna fun.