Kudirat Abiola: Akọni obìnrin tó jẹ́ igilẹ́yìn ọgbà fún ọkọ rẹ̀

Yusuf Olalekan Image copyright Yusuf A
Àkọlé àwòrán A bí Kudirat Abiola ni ọdún 1951 ní ]ilú Zaria, òun ni ìyàwó keji ti Abiola fẹ́ tó si bi ọmọ mẹ́fa.

Kò sí àní àní pé, ti à bá ti ń sọ̀rọ̀ iromi Moshood Kasimawo Olawale (MKO) Abiola to n jo lori omi, à máa gbúròó Kudirat Abiola, akọni obinrin tó jẹ onilu to ń lu ilu fun lábẹ omi.

Alhaja Kudirat Abiola pé ọdún mẹ́tàlélógún lónìí to wọ káà ilẹ̀ sùn, ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé ìkú rẹ̀ kìí ṣe àmúwá ọlọrun nítori àwọn agbanípa ló pa a, nígbà ti ìjọba fi ọkọ rẹ̀ sẹ́wọ̀n.

Wọn mú ọkọ rẹ̀ nígbà ti wọn rii pe oun ló ń jawé olúbori nínú ìdìbò àpàpọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọdun 1993.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ẹ dá owó padà f’áwọn ẹbí MKO Abiọla'

A bí Kudirat Abiola ni ọdún 1951 ní ilú Zaria, òun ni ìyàwó keji ti Abiola fẹ́, tó si bi ọmọ mẹ́fa.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣirísi ìwádìí ló wáyé lẹ́yìn ikú Kudirat, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ̀yìn ti ó ti kú, gẹ́gẹ́ bí ohun ti ìròyìn sọ, wọn pàṣẹ fún ènìyàn ẹlẹni mẹ́fà kan láti parí iṣẹ́ ọhun ni.

Wọ́n pa Kudirat sínú ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbọn, bẹ́ẹ̀ ni awakọ̀ rẹ̀ náà bá ìṣèlẹ̀ yìí lọ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ tí wọn fẹ̀sùn kàn pé ó lọ́wọ́ nínú iku rẹ̀, to wà nínú ọkọ pẹ̀lú rẹ̀, kò fi ara pa rárá.

Lẹ́yìn ikú Kudirat Abiola ní wọn yíi orúkọ ilé iṣẹ́ rẹdíò tí wọn pé ni Radio Democracy, ti wọ́n ṣẹṣe dá sílẹ̀ ní Norway, pada sí Radio Kudirat.

Eyi waye pẹ̀lú àtilẹ̀yin àwọn orilẹede bii Amẹríkà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Swedish, Danish àti ijọba Norway, lọna áti fí òpin si ìṣèjọba ológun ní Nàìjíríà pada, sí Radio Kudirat.

Ní ọdún 1998, òpópónà kan ni New York náà tún yi orukọ pada láti máà jẹ́ Kudirat Abiola Corner.

Lọ́dún 1998 bákan náà, Hamzat Al-Mustapha fara hàn nílé ẹjọ́ pẹ̀lú ọmọ ààrẹ ológun àna Abacha, Mohammed ti wọn fi ẹsùn ikú Kudirat Abiola kan.

Níbi ìgbẹ́jọ́ náà àwọn ti wọn jẹ́rìí pé àwọn ní àwọn pa Kudirat ni Sergeant Barnabas Jabila sọ pé àṣẹ Al-Mustapha ni àwọn tẹ̀lé.

Ní ọgbọ̀n ọjọ́ nínú oṣù kẹfà ọdún 2012, wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún Hamza Al-Mustapha àti Alhaji Lateef Shofolahan lóri pípa Kudirat Abiola.

Ọlórí ẹ̀sọ́ ààrẹ ni Al-Mustapha jẹ́ nígbà ti Shofolahan jẹ olùránlọ́wọ́ pàtàkì fún olóògbé náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú