UN General Assembly: Buhari ní ìgbà ọtun ni ìyànsípò Bande jẹ́ lẹ́ka òṣèlú

Tijanni Bande Image copyright @BashirAhmad
Àkọlé àwòrán Tijanni Bande

Tijanni Muhammed Bande ni wọ́n yan gege bi ààrẹ fún ipejopọ ajọ ìsọ̀kan agbaye ( UN General Assembly).

Tijani Bande je ọjọgbọn àti oga agba ile ẹkọ fasiti Usman Danfodiyo ti ìpínlẹ Sokoto nigba kan ri, kò ni enikẹni tí ó ba du ipò náà nínú ìdìbò tó wáyé lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun ní ìbi ìjokò ile ẹlẹkẹrinléni ààdọrin irú rẹ̀.

Muhammad Bande ni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kejì tí yóò dé orí ipò náà, lẹ́yìn Joseph Garba tó jẹ ajagunfẹ̀yìntì, tó si tún jẹ asojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lókè òkun.

Ọpọ ọmọ Naijiria le maa wo wi pe ki lorukọ aṣọ Tijanni Bande nile alaro Naijiria, Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Tijjani Bande tó di Ààrẹ ẹ̀ka Isọ̀kan Àgbáyé UNGA?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Garba jẹ oyè náà láàrin ọdún 1989 sí ọdún 1990.

Sáájú ìdìbò náà ní ààrẹ Muhammadu Buhari ti rán àwọn asojú ìjọba àpapọ̀ lọ láti lọ gbárùkù tí Muhammadu Bande.

Akọ̀wé àgbà fún ilé iṣẹ́ tó n ri si ọ̀rọ̀ ilẹ̀ okèrè Mustapha Suleiman, lo sáaju àwọn asoju ijọba,

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Ààrẹ Muhammadu ni ìgbà ọtun yìí yóò fún orilẹ̀-èdè Nàìjíríà àǹfàní, láti pè fún ètò òṣèlú, ìgbáyegbadùn tó dára, eto ọ̀rọ̀ ajé to yanrantí àtí láti mu ọ̀rọ̀ àyíka tó n da gbogbo àye láàmu gbọ.

Ààrẹ Buhari ni orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ń woye lọ́nà to gbòòrò, láti ba àwọn ọmọ ajọ ìsọkan àgbáye tó kù ṣiṣẹ́,eyi ti yoo mu ìtẹ̀síwáju ba ètò àlááfíà lágbàyé, ètò ààbò, dídènà wàhálà àti lati mú ki ìbáṣepọ̀ túbọ̀ gbópọ̀n si ni àgbáyé, riro àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn obinrin lagbara, pẹ́lú fífàyè gba ẹ̀tọ́ ara ilú.