Abacha Loot: Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rí owó Abacha bíi owó ọ̀daràn, ló ṣe gbẹ́sẹ̀ le

Sani Abacha Image copyright Nigeria High Commision
Àkọlé àwòrán Owo Abacha

Ẹgbẹlẹgbẹ owo to to biliọnu mejilelọgọrin naira (£211m) to jẹ ti olori tẹlẹ fun orilẹede Naijiria, oloogbe Ọgagun Sani Abacha, ni wọn ti ri nile ifowopamọ Jersey bank nilẹ okeere.

Abacha, to jẹ olori orilẹede Naijiria laarin ọdun 1993 si 1998 to ti jalaisi, niroyin sọ pe o kowo naa lọ si Channel Islands nilẹ Yuropu, lati ilẹ Amẹrika.

Iwe iroyin Metro nilẹ Gẹẹsi fidi rẹ mulẹ pe, ninu apo aṣuwọn ile iṣẹ Doraville Properties Corporation ni ile ifowopamọ Jersey ti ri owo naa.

Ni bayii, ijọba ilẹ Gẹẹsi ti gbẹsẹ le owo naa titi digba ti awọn alaṣẹ Jersey, ilẹ Amẹrika ati Naijiria ba sọ asọyepọ lori bi wọn yoo ṣe pin owo naa.

Ijọba ilẹ Gẹeṣi maa n gbẹsẹ le owo kowo ti wọn ba ri ni ilu Jersey, ijọba maa n ri owo bẹe bi owo ti awọn ọdaran ji ko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Ijọba maa n lo iru owo bẹẹ fun idagbasoke agọ ọlọpaa kaakiri ilẹ Gẹẹsi, ati fun awọn oriṣiiriṣii akanṣe iṣẹ miiran.

Ẹgbẹlẹgbẹ owo ti oloogbe Abacha ko pamọ silẹ okeere nigba to wa lori oye ni ijọba Naijiria ti gba.