Ìtàn Mánigbàgbé: Adesoji Aderemi tiraka láti dí àlàfo láàrin olówó àti olòṣì

Ọba Adesọji Aderẹmi Image copyright @oluwole_dada
Àkọlé àwòrán O jẹ ara awọn eeyan to kọkọ laju, o kọ ẹkọ iwe, o lowo, o lọla, o gbajumọ, o si jẹ asaaju ilu.

Ti a ba n sọrọ awọn oriade nilẹ Yoruba, ọkan pataki ni Ọba Ọlọla Titus Martins Adesọji Tadeniawo Aderẹmi, Atọbatẹlẹ Kinni, tii se Ọọni tilu Ile Ifẹ.

Oun ni ọba alaye akọkọ ti yoo pa ipo ọba mọ sise olootu ijọba lekun iwọ oorun guusu Naijiria ijọhun.

Eeyan ko si lee pe ori akọni, ko ma fi ida lalẹ gaaraga ni ọrọ ọba Aderẹmi, ta aba wo bi ori ade naa se lami-laaka si nigba to wa loke eepẹ.

O jẹ ara awọn eeyan to kọkọ laju, o kọ ẹkọ iwe, o lowo, o lọla, o gbajumọ, o si jẹ asaaju ilu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko si si bi a se maa sọ nipa itan awọn ọmọ Oodua to jẹ akinkanju ati ọlọpọlọ pipe, ti a ko ni sọrọ Ọba alaye naa.

Ko wọpọ rara lasiko tirẹ ki odidi ọba ilu nla bii ilu Ile Ifẹ tun maa se akoso ẹkun rẹ, tii se ipo oselu.

Gẹgẹ bi a se ka a ninu akọsilẹ oju opo ayelujara Wikipedia, ipa ti Ọba Adesọji Aderẹmi ko lati di alafo to wa laarin olowo ati ọlọrọ kii se keremi, to si fi igbe aye rẹ silẹ fun ilọsiwaju awọn ọms Yoruba ati ilẹ Kaarọ Oojire lapapọ.

Image copyright @NNPtweets
Àkọlé àwòrán O jẹ ara awọn eeyan to kọkọ laju, o kọ ẹkọ iwe, o lowo, o lọla, o gbajumọ, o si jẹ asaaju ilu.

Ko si ni dara ki iran asiko yii ma mọ ẹni ti Ọba Adesọji Aderẹmi se ati awọn ipa ribiribi to ti ko si agbega iran rẹ, bi o tilẹ jẹ pe onirese rẹ ko fin igba mọ, amọ ko yẹ ka jẹ ki eyi to fin silẹ parun.

Ta ni Ọba Adesọji Aderẹmi?

 • Asiko ogun nla kan nilẹ Yoruba ni Ọmọọba Gbadebọ lati idile ọba Ọsinkọla nilu Ile Ifẹ ati aya rẹ, Adekunbi to wa lati ilu Ipetumodu, bi ọmọkunrin lanti lanti kan lọjọ Kẹẹdogun, osu Kọkanla ọdun 1889
 • Baba ọmọ tuntun yii ti jagun lọ nigba naa, ti ko si si nile, amọ wọn sọ ọmọ naa ni suna Adesọji Tadeniawo Aderẹmi. Ni kete ti baba rẹ si ti oju ogun de lo tọ Ifa lọ lati mọ ẹsẹntaye ọmọ tuntun naa tabi ayanmọ to gbe wa sile aye
 • Ni kete ti wọn gbe ọpẹlẹ janlẹ, ni Ifa sọ fun Ọmọọba Gbadebọ pe ko tete fori balẹ fun ọmọ tuntun naa, eyi to tumọ si pe Adesọji, ọmọ tuntun jojolo to gbe lọwọ, yoo gun ori itẹ awọn baba nla rẹ, yoo jẹ olokiki, ti yoo si ni ibasepọ pẹlu awọn iran ajeji ni ọna jinjin rere, eyi ta lee pe ni awọn oyinbo alawọ funfun. Kia si ni baba rẹ ti ni ki wọn gbe ilẹkẹ si Adesọji lọrun lati fihan pe ọmọ ọba ati ọba lọla ni
 • Se ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, ọmọ ọdun mẹjọ ni Adesọji wa, to fi padanu baba rẹ, iya rẹ nikan si lo n gbọ bukata rẹ titi tawọn oyinbo ẹlẹsin Kristiẹni fi de, to si fi Adesọji sile iwe alakọbẹrẹ St Phillips, Ile Ifẹ lọdun 1901
 • Ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samu-samu, Adesọji korira isẹ agbẹ tawọn ẹgbọn rẹ n se nigba naa, ọna iwe si lo fẹ gbajumọ, bẹẹ lo nifẹ lati lọ kawe nipa isẹ amofin sugbọn nitori pe o ti wa lori ẹmi rẹ lati jọba, ko seese fun
 • Adesọji gbajumọ isẹ, o ti lowo lọwọ, to si ti di gbajumọ nigba ti Ọba Ademiluyi to wa lori itẹ Ọọni fi waja, oun si ni wọn yan bi ọọni tuntun, to si gori itẹ awọn baba nla rẹ lọjọ Keji osu Kẹsan ọdun ọdun 1930 gẹgẹ bii Ọọni Kọkandinlaadọta tilu Ile Ifẹ
 • Adesọji ni Ọọni akọkọ ti yoo jẹ ọmọwe, oun si ni ọba alaye nilẹ Yoruba to kere julọ nigba naa, ti yoo gun ori itẹ awọn baba nla rẹ lẹni ogoji ọdun
 • Lasiko Ọba Adesọji Aderẹmi si ni agbega nla nla ba ilu Ile Ifẹ, to si mu agbega ba eto ẹkọ, eyi to mu ki wọn da ile ẹks girama Oduduwa College silẹ losu Kinni ọdun 1932, oun si lo fi owo ara rẹ silẹ fun kikọ ileẹkọ naa
 • Bakan naa, agbekalẹ ile ẹkọ fasiti Ifẹ silu naa tun jẹ ọkan lara awọn ohun ilọsiwaju to waye lasiko ti Ọba Adesọji Aderẹmi wa lori itẹ, eyi ti ko sẹyin aayan rẹ, bakan naa si lo tun jẹ alaga titi laelae fun igbimọ awọn lọbalọba lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, bẹrẹ lati ọdun 1966 si 1980 to darapọ mọ awọn baba nla rẹ
 • Ọba Adesọji Aderẹmi jẹ gomina fẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ijọun laarin ọdun 1960 si 1962, nitori pe o tun jẹ ogbontarigi oloselu yatọ si pe o jẹ ọba alaye
 • Lasiko isejọba amunisin, Ọba Adesọji Aderẹmi gba agbara kun agbara lọwọ awọn ajẹlẹ, tawọn oyinbo gan si kọ nipa asa ati ise ilẹ Kaarọ Oojire lọwọ rẹ
 • Ọba Adesọji Aderẹmi ni ọpọ iyawo ati ọmọ, alagbo nla si la lee pe, ọkan ninu awọn ọmọ rẹ si ni Arabinrin Tẹjumade Alakija

Bi o tilẹ jẹ pe ofin ilẹ wa ko gba awọn ọba alaye laaye mọ lati maa kopa ninu oselu, amọ o yẹ ki wọn fi igbe aye Ọba Adesọji Aderẹmi se awokọse rere, nipa lilo agbara wọn fi mu ilọsiwaju alailẹgbẹ ba agbegbe wọn.

O si tun yẹ ka kọ ẹkọ pe aisi baba abi iya ko ni ki ọmọ ma mọ ohun to fẹ se lati di eeyan nla lọjọ ọla.

Image copyright @GbenroAdegbola

A wa gbadura pe Ọlọrun yoo tubọ dẹ ilẹ fun ni ọba Ọlọla Titus Martins Adesọji Tadeniawo Aderẹmi, Atọbatẹlẹ Kinni, tii se Ọọni tilu Ile Ifẹ to se gudugudu meje ati yaya mẹfa fun iran Yoruba.