8th National Assembly: Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kẹ̀jọ kógbá sílé lónìí

Bukola Saraki Image copyright Twitter/The Senate President
Àkọlé àwòrán Ile Igbimọ aṣofin kẹjọ

Oni ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun 2019 ni ile igbimọ aṣofin agba ikẹjọ l'Abuja yoo kogba sile.

Koda, adari ile Sẹnẹtọ Bukọla Saraki naa yoo dagbere fun ile aṣofin lẹyin to fidi rẹmi ninu idibo gbogboogbo to lọ.

Ọpọ lo ti tako awọn aṣofin laarin ọdun to kọ ja ti wọn ti n ṣofin ni olu ilu Naijiria, Abuja.

Ṣugbọn iwadii fidi rẹ mu lẹ pe ile igbimọ aṣofin agba kẹjọ to n ko gba sile lonii lo ṣaṣeyọri julọ ninu itan eto oṣelu orilẹ-ede Naijiria.

Eyi ni diẹ lara awọn aṣeyọri ile igbimọ aṣofin agba kẹjọ l'Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Gbigbe eto iṣuna ile sita

Lẹyin ọpọ atotonu awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ile igbimọ aṣofin fi eto iṣuna ile sita lọdun 2017.

Eyi ni igba akọkọ ti iru rẹ yoo ṣẹlẹ lati ọdun 2010 ti adari ile tẹlẹ, David Mark ti n ṣe ọrọ eto iṣuna ile ni oku oru.

Image copyright Twitter/The Senate President

Ijiroro gbagade lori eto iṣuna ile

Ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja ṣe ijiroro gbagade ẹlẹẹkẹta iru rẹ lori eto iṣuna ile ninu oṣu kẹta, ọdun 2019.

Ile bẹrẹ eto yii labẹ adari Sẹnẹtọ Bukola Saraki lọdun 2016. Eto yii ti fun ọpọ ọmọ Naijiria lanfaani lati beere oniruuru ibeere lori eto iṣuna ile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAjayi: ṣé ìwọ mọ irúfẹ́ ọmọ tí Yorùbá ń pè bẹ́ẹ̀?

Ofin ọdọ o kere lati ṣejọba

Ile igbimọ aṣofin gbe abadofin ọdọ o kere lati ṣejọba lọ siwaju Aarẹ Muhammadu Buhari, eleyi ti aarẹ buwọlu lọdun 2018.

Ofin naa din ọjọ ori awọn oludije fun ipo aarẹ ku lati ogoji ọdun si ọdun marundinlogoji, ati tawọn gomina ku lati ọdun marundinlogoji si ọgbọn ọdun.

Ṣisẹ ofin to pọju lọ

Image copyright Twitter/The Senate President

Ile igbimọ aṣofin agba kẹjọ ṣiṣẹ lori abadofin to din meje lọọdunrun un(293) lati igba ti wọn ti bẹrẹ di oṣu karun un, ọdun 2019.

Meji din ni aadoje(128) ni ile igbimọ aṣofin keje le ṣiṣẹ le lori, nigba ti ile kẹfa ṣiṣẹ ofin mejilelaadọrin (72).

Eto aabo

Lootọọ, kii ṣe ojuṣe ile aṣofin lati pese eto to mọnyan lori fawọn ara ilu, ṣugbọn ile aṣofin kẹjọ ṣe apero lori eto aabo ninu oṣu keji ọdun 2019.

Yatọ si apero yii, ile jiroro lọsọọsẹ lori bi eto aabo yoo ṣe gbopọn si lorilẹedee Naijiria bo tilẹ jẹ pe diẹ ninu aba wọn ni igbimọ alaṣẹ ṣiṣẹ le lori.

A kii mọ rin, kori o ma min, eyi ni awọn kudiẹkudiẹ ti ile igbimọ aṣofin agba kẹjọ ni, bi wọn ti kogba sile lonii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú