Yinka Ayefẹlẹ: Àdúrà lẹ ṣe pé mo bí ìbẹta, yóò sì rí bẹ́ẹ̀

Yinka Ayefele Image copyright yinkaayefele
Àkọlé àwòrán Yinka Ayefẹlẹ: Àdúrà lẹ ṣe pé mo bí ìbẹta, yóò sì rí bẹ́ẹ̀

Gbajugbaja akọrin Tungba nni, Yinka Ayefẹlẹ ti kigbe sita faraye pe oun ko bi ibẹta gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti n tan iroyin naa kalẹ lawọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara.

Yinka Ayefẹlẹ, loju opo Instagram rẹ ti salaye pe ofo, ọjọ keji ọja ni iroyin kan to n ja rain-rain nilẹ pe iyawo oun bi ibẹta ni orilẹede Amẹrika ni owurọ ọjobọ.

O ni aworan oun ati iyawo oun ti wọn lo lati fi kọ iroyin naa jẹ eyi ti awọn jọ ya ni ọdun meje sẹyin lasiko ikomọ ọmọ aburo oun nilu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayefẹlẹ wa rawọ ẹbẹ sawọn ololufẹ rẹ pe ki wọn kẹyin si iroyin eke naa ati aworan ofege to n gbe kiri.

Image copyright yinkaayefele

"Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin pe ẹ ro ire ro emi ati ẹbi mi, mo si gbadura pe yoo ri bẹ ti wi ni orukọ Jesu."

Ọpọ awọn eeyan loju opo Instagram naa si lo n gbarata lori iroyin ofege naa.Gbajugbaja akọrin Tungba nni, Yinka Ayefẹlẹ ti kigbe sita faraye pe oun ko bi ibẹta gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti n tan iroyin naa kalẹ lawọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters