Oyo Algon: Àlááfíà Ọyọ yóò dàrú, tí Buhari kò bá yanjú àáwọ̀ yìí

Awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ Image copyright Oyo State Government

Yoruba ni bi ọrọ ba se n pẹ nilẹ, yoo maa gbọn si ni. Bẹẹ ni ọrọ aawọ to n waye laarin gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ati awọn alaga ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ naa wa bayii.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii fi ye ni pe ọrọ naa ko ti ni ojutu, ti awọn alaga ibilẹ naa si ti pawọpọ kọ lẹta kan si aarẹ Muhammadu Buhari pe ko gba awọn silẹ lọwọ gomina Seyi Makinde.

Awọn alaga ijọba ibilẹ naa ni se ni gomina ati ẹgbẹ oselu rẹ, PDP, n lo awọn janduku lati maa wa dun mahuru mahuru mọ awọn lati mase yọju si ọọfisi gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹta naa, ti Ọmọọba Ayọdeji Abass Alẹsinlọyẹ ati Ọlayinka Jestoye dijọ fọwọsi, lọjọ Karun osu Kẹfa ọdun 2019, lorukọ awọn alaga ijọba ibilẹ yoku naa fikun pe,

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lati fidi ootọ mulẹ nipa lẹta naa, Ọmọọba Ayọdeji Abass Alẹsinlọyẹ salaye pe yoo dara ki aarẹ dasi ọrọ naa, tori asẹ ileeẹjọ ti wa nilẹ tẹlẹ, eyi to ni gomina Makinde ko gbọdọ yọ awọn lori oye.

Image copyright Seyi Makinde

Bakan naa, Alẹsinlọyẹ ni awọn tun n fẹ ki Buhari gba gomina Makinde nimọran, lati bọwọ fun ifẹ awọn ara ilu, ko si gba awọn gomina naa ni aaye lati sisẹ bii alaga ijọba ibilẹ tawọn eeyan dibo yan.

O fikun pe, awọn alaga ijọba ibilẹ naa ti pinnu pe ikoko ko ni gba omi, ko gba ẹyin, ko tun gba sọsọ, ti gomina Makinde ba fi tẹsiwaju lati fẹ fi tipa gba akoso awọn ijọba ibilẹ naa, nitori eyi yoo pagidina eto alaafia nipinlẹ Ọyọ.