CAF Champions League: CAF pàṣẹ àtúngbá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá CAF Champions League

Awọn agbabọọlu Esperance n ṣajọyọ pẹluu ife ẹyẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán CAF ní ifẹ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá tí wọ́n kọ́kọ́ gbá tako àṣẹ àtò ìdíje bọ́ọ̀lu

Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu afẹsẹgba ni ilẹ Afirika, CAF ti paṣẹ ki wọn tun ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije CAF Champions league to waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu karun ọdun 2019 gba.

Bi o tilẹ jẹ pe igbesẹ ati aṣẹ ọhun ṣe ọpọlọpọ onwoye ere bọọlu afẹsgba ni haa-hinn, ajọ CAF ni bi eto ati ato gbogbo ṣe lọ si lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa ku diẹ kaa to eyi lo si faa ti oun fi gbe igbesẹ atungba ifẹsẹwọnsẹ naa.

Nibi ipade igbimọ alaṣẹ ajọ CAF to waye ni ilu Paris lorilẹede France lọjọru ni aṣẹ yii ti jade.

Image copyright Getty Images

Lara awọn ohun ti gbogbo ọmọ igbimọ naa fẹnuko si ni iwọnyii:

  • Eti fun irọwọrọsẹ idije naa ati abo ko peye lasiko ipele keji aṣekagba idije CAF Champions league to waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu karun ọdun 2019 eyi ti ko fi aaye silẹ fun ifẹsẹwọnsẹ naa lati wa si opin gẹgẹ bi ofin ere bọọlu ṣe laa silẹ.
  • Nitori idi eyi, wọn gbọdọ tun ifẹsẹwọnsẹ naa gba ni papa iṣire miran ti ko ni jẹ ti orilẹede Tunisia;
  • Igbimọ alaṣẹ ajọ CAF yoo gbe ọjọ ati ibi ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye sita laipẹ;
  • Nitori idi eyi, ẹgbẹ agbabọọlu Espérance de Tunis gbọdọ da ife ẹyẹ ati awọn ami ẹyẹ gbogbo ti wọn fun wọn pada si olu ileeṣẹ ajọ CAF lẹyẹ o ṣọka;
  • Gbogbo awọn ọrọ gbogbo to ku lori ibawi, ato ati bi awọn oludari ere bọọlu yoo ṣe ri yoo tẹ awọn igbimọ gbogbo to ba yẹ lọwọ fun igbesẹ ati ipinnu wọn.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOffa Robbery: Àwọn aráàlú ṣi n gbé nínú ìpaya lẹ́yìn ọdún kan