Emir Kano: Ganduje fẹ̀sùn ìkọ́wójẹ kan Emir Sanusi

Sanusi Lamido Image copyright @Lamidoofficial
Àkọlé àwòrán Ajọ tó ń gbógun ti ìwá àjẹbánu àti gbigbọ́ ẹ̀sun ara ìlú ní ìpínlẹ̀ Kano ló fẹ̀sún kan Emir tí wọn si dábàá pé kí Emir lo rọ́kun nílé.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Ganduje tí fún Emir Kano, Muhammadu Lamido Sanusi keji ní ìwé wá wi tẹnu rẹ lọ́nìí ọjọ́bọ̀, lóri ẹ̀sùn pé ó ṣe owó mọ́kumọ̀ku.

Ajọ tó ń gbógun ti ìwá àjẹbánu àti gbigbọ́ ẹ̀sun ara ìlú ní ìpínlẹ̀ Kano, ló fẹ̀sún kan Emir tí wọn si dábàá pé kí Emir lo rọ́kun nílé.

Olóri oṣisẹ̀ láàfin Emir, Munir Sanusi tó jẹ́ri si gbigba ìwé ẹsùn náà, sọ pe, ìjọba ní ki Emir fesi láàrin wákàti mẹ́rìnlélogun lóri ẹ̀sùn náà.

''A ti gba ìwé ẹ̀sún náà, ìjọba si ti bèèrè fún èsì láàrin wákàtí mẹ́rinlélógún. Awọn ìjòye Emir ń fojú sùnukùn wó ẹ̀sùn náà".