Saraki: Àwọn aṣòfin àpapọ̀ ṣ'àfihàn ìṣọ̀kan lásìkò tí jàǹdùkù jí ọ̀pá àṣẹ ilé gbé

Sẹnetọ Bukọla Saraki Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Sáà kẹjọ ilé aṣòfin àpapọ̀ parí ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà ọdún 2019

Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki ti ṣalaye ọjọ ti inu rẹ bajẹ julọ lasiko to fi jẹ aarẹ fun ile aṣofin apapọ lorilẹ-ede Naijiria.

Ninu ọrọ idagbere rẹ lo ti sọ eyi nibi eto idagbere ti ile aṣofin saa kẹjọ ṣe ni ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saraki wa lara awọn aṣofin ti ko ni pada fun saa tuntun mọ ni ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Naijiria ti yoo bẹrẹ saa kẹsan an ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa, ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Saraki ni ọjọ ti awọn janduku wa da ile aṣofin ru ti wọn si ji ọpa aṣẹ ile naa gbe ni o ba oun ninu julọ.

O ni ọjọ yii yoo duro ninu itan gẹgẹ bii ọjọ ti awọn eeyan kan jẹ eewọ nitori aidọgba ironu lori oṣelu.

O ni lẹyin o rẹyin iṣẹlẹ naa ja sayọ ni nitori o fun awọn aṣofin lanfani lati fi ẹsẹ wọn tilẹ pe aguda awọn ko jẹ labẹ Gẹẹsi ẹnikẹni tabi ẹka iṣejọba kankan.

"Ọjọ naa yi pada lati di ọjọ afihan okun ọmọ iya to wa laarin ile yii ati awọn aṣoju-ṣofin, pẹlu bi awọn aṣofin naa ṣe dide lati gbaruku ti awọn aṣofin agba lati koju awọn to wọ ile naa."

Bakan naa, lo ni lara ohun ti awọn to dide ogun si ile aṣofin apapọ ṣe ni ti awọn agbofinro to ṣingun wọ gbagede ile aṣofin apapọ ni oṣu kẹjọ, ọdun 2018.

Saraki ni eyi yoo wa ninu iwe itan, ṣugbọn awọn aṣofin dide lati gba ara wọn silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters