DAAR Communications: AIT, RayPower padà lẹ́yìn àṣẹ ilé ẹjọ́

logo
Àkọlé àwòrán,

NBC: AIT kọ̀ láti tẹ̀le ìlànà òfin ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Naijiria

Ileeṣẹ amohunmaworan AIT ati ti asọrọmagbesi RayPower FM pada si ori afẹfẹ.

Lẹyin ti Ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa ni Abuja paṣẹ pe ki ajọ to n mojuto ọrọ igbọhunsafẹfẹ ni Naijiria (NBC) ti ọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ fun igba diẹ lori ọrọ DAAR Communications, AIT ati RayPower FM ti pada sori afẹfẹ.

Ajo naa ti awọn ileeṣẹ DAAR Communications, AIT ati Raypower lori ẹsun aṣemaṣe ni ọjọbọ, eyi to mu ọpọ awọn eniyan bẹnu ẹ̀tẹ́ lu igbesẹ ajọ naa.

Ṣugbọn ile ẹjọ ni kí ajọ NBC lọ ni suuru titi di igba ti wọn yoo fi dajọ lori ẹjọ ti DAAR Communications fi ta ko igbeṣẹ ajọ naa.

Ninu idajọ rẹ lori ọrọ naa ni ọjọ Ẹti, Adajọ Inyang Ekwo ni ki gbogbo awọn ti ọrọ kan pada si bi ọrọ ṣe ri ni ọgbọn ọjọ, oṣu karun un.

Adajọ naa kepe ajọ NBC, ileeṣẹ ijọba apapọ lori iroyin ati agbẹjọro agba ti Naijiria, lati farahan ki wọn si sọ idi ti ile ẹjọ ko fi gbọdọ da aṣẹ NBC lori ọrọ naa danu ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa nigba ti wọn yoo tun gbọ ẹjọ naa.

Àkọlé àwòrán,

DAAR Communications: AIT kò kọ̀ láti tẹ̀le ìlànà òfin ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Naijiria

Ṣíwájú lórí ọ̀rọ̀ náà:

Ẹgbẹ awọn akọroyin ti pàṣẹ ìyípadà laarin ọjọ kan.

Ẹgbẹ awon akoroyin Naijiria ti a mọ si Nigerian Union of Journalists ti paṣẹ pe ki ajọ NBC tun ero wọn pa.

Wọn ni awọn fun ajọ NBC ni wakati mẹrinlelogun pere ki wọn fi gbesẹ kuro lori ọrọ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ AIT ati Ray Power.

Chris Isiguzo to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa lo ni awada ni oun kọkọ pe ọrọ naa tẹlẹ nigba ti oun gbọ ki oun to fidiẹ mulẹ pe ootọ ni.

O ni oun ko gbagbọ pe iru eyi le waye lasiko ijọba awa ara wa nilu to ni Ọba to ni ijoye.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

NUJ: Ẹ̀yin Akọ̀ròyìn, ẹ sọ́ra nípa kíkọ ìròyìn tó léwu fétò ààbò

O ni igbesẹ NBC yii ko faaye gba ominira awọn akoroyin to yẹ ko wa ni Naijiria bayii.

Àkọlé fídíò,

Odebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Alaga NUJ ni oun gbagbọ pe awọn ọna miran wa to yẹ ki ajọ NBC gbe lati fidi ofin wọn mulẹ ju ki wọn ṣe oun to tabuku gbogbo ẹgbẹ.

O ni oun kọ lati fọwọ lẹran lori ọrọ yii ati p\w ohun ti ẹgbẹ n fẹ ni ki ajọ NBC tete yi ipinnu rẹ pada.

Bawo ni ọrọ ṣe jẹ tẹlẹ?

Ileeṣẹ amohunmaworan AIT wa lara awọn ileeṣe aladani akọkọ ni Naijiria.

Wọn gba àṣẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ AIT àti Ray Power.

Àkọlé àwòrán,

NBC: AIT kọ̀ láti tẹ̀le ìlànà òfin ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Naijiria

Àjọ National Broadcasting Commission to n mójútó ọ̀rọ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Naijiria ti gba àṣẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lọ́wọ́ iléeṣẹ́ AIT àti Ray Power lọjọbọ.

Wọn ni ki ileeṣẹ African Independent Television ati Ray Power FM lọ rọọkun nile na.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

NUJ: A fẹ mọ ẹsẹ awọn akọroyin tẹ da duro

Omowe Modibo Kawu to jẹ adari ajọ NBC ti ṣalaye pe ileeṣẹ amohunmaworan AIT kii san owo idiyele ominira lati ṣiṣẹ wọn lasiko.

O ni bakan naa ni AIt kii bọwọ fun ofin igbohunsafẹfẹ.

Àkọlé fídíò,

Pẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters

Kawu ni AIT ṣafihan iṣẹ iwadii kan lasiko idibo to kọja ni Naijiria, eyi ti ọrọ eto idibo aarẹ nipa rẹ dẹ ṣi wa nile ẹjọ.

O tun ni wọn maa n ṣafihan awọn nkan to le fa wahala lawujọ ninu eto araarọ wọn ti wọn pe ni Kakaki Social.

Oga agba fun ajọ NBC ni ọpọ igba ni awọn ti ri ẹsun gab lati ọdọ awọn ara ilu lori akoonu eto tile iṣẹ AIT ati Ray Power n gbe jade.

Àkọlé àwòrán,

O tun ni wọn maa n ṣafihan awọn nkan to le fa wahala lawujọ ninu eto araarọ wọn ti wọn pe ni Kakaki Social.

O ni ajọ NBC ti fawọn leti lọpọ igba paapaa lasiko eto idibo Naijiria to kọja ki wọn le so ewe agbejẹ mọwọ.

Bayii ni ajọ NBC ti kede pe ileeṣẹ mejeeji to jẹ ti DAAR Communications ko gbọdọ ṣiṣẹ titi awọn yoo fi gbẹsẹ kuro lori ofin to de wọn yii.

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Ki lo ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Laarọ ọjọbọ ni ọga agba fún ileeṣẹ DAAR Communications, Raymond Dokpesi ti ṣaaju awọn eniyan rẹ lọ ṣe iwọde ko tẹ mi lọrun kaakiri ilu Abuja.

Ni olu ilu Naijiria, ni Dokpesi ti fẹhonuhan pe ko yẹ kijọba tile iṣẹ oun pa.

Kinni AIT ri sọ si ọrọ yii?

Raymond Dokpesi to ni DAAR Communications ti ṣalaye pé awọn ko tete san owo idiyele igbohunsafẹfẹ ti saa yi nitootọ.

O ni idi ti eyi fi ri bẹẹ ni pe gbogbo wọn gba pe ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira ti ajọ NBC ni ki ileeṣẹ aladani san ti pọju ni.

Àkọlé fídíò,

Ajayi: ṣé ìwọ mọ irúfẹ́ ọmọ tí Yorùbá ń pè bẹ́ẹ̀?

O ni eyi lo jẹ ki ẹgbẹ awọn onile iṣẹ akọroyin BON fẹnuko pe eto ọrọ aje Naijiria ko burẹkẹ to lasiko yii.

Bakan naa ni Dokpesi sọrọ lori eto Kakaki ti NBC fi ẹsun kan pe, eto naa wa fun ero inu awọn ara ilu.

O mẹnuba ominira lati sọrọ ti ara ilu yẹ ko ni ni Naijiria bayii.