Celestine Egbunuche: Òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ti lo ọdún 18 l‘ẹ́wọ̀n, kó tó rí ìdáǹdè

Celestine Egbunuche ati ọmọ rẹ Paul ni ọgbọ ẹwọn Image copyright Global Society for anti corruption

Yoruba ni bi isẹ ba sẹ ọmọ fun ogun ọdun, ti iya ba jẹ ọmọ fun ọgbọn osu, bi ko ba pa ọmọ, yoo kuku pada lẹyin ọmọ ni.

Bẹẹ ni ọrọ baba ẹni ọgọrun ọdun kan ri, Celestine Egbunuche, ẹni ti ijọba tu silẹ ni ọgba ẹwọn lẹyin ọdun mejidinlogun to ti fi asọ penpe ro oko ọba.

Ohun to wa jẹ kayeefi pẹlu baba yii ni pe oun ati ọmọkunrin rẹ, Paul, ni wọn dijọ dajọ ẹwọn fun lori ẹsun pe wọn gbindanwo lati seku pa eeyan kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Celestine Egbunuche, ni ẹgbẹ kan ti kii se tijọba, eyi to n gbogun ti iwa ajẹbanu, Global Society for Anti Corruption (GSAC), ja fun idande rẹ rẹ ati ọmọ rẹ lọgba ẹwọn.

Amọ baba naa, ẹni to ti n se aisan atọgbẹ, ti ko si riran daada, ni ijọba tu silẹ lọgba ẹwọn to wa nilu Enugu, ti ọmọbinrin rẹ, Chisom Celestine ati awọn asoju ẹgbẹ GSAC, si lọ pade rẹ ni kede ti wọn tu silẹ lọgba ẹwọn ọhun.

Image copyright Global Society for anti corruption

Nigba to n ba ikọ iroyin BBC sọrọ, Chisom Celestine salaye pe inu oun dun pupọ pe baba oun pada ri itusilẹ lọgba ẹwọn sugbọn o se oun laanu pe oun ko ni agbara lati lee setọju baba naa bo se yẹ.

Lọwọ-lọwọ bayii, wọn ti gbe baba Celestine lọ sile iwosan fun itọju, ti ko si si ẹni to lee sọ ohun ti yoo sẹlẹ sii nitori Paul, ọmọ baba naa lo n tọju rẹ lasiko ti awọn mejeeji wa lọgba ẹwọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Saa isejọba gomina Rochas Okorocha ni ipinlẹ Imo, to bẹbẹ fun isiju aanu wo baba naa ti kogba wọle, ti ijọba tuntun si ti wa nijọba, a ko si mọ boya o seese ki wọn seto iranwọ fun baba naa.