South Africa Lions: Àwọn aláṣẹ rọ àwọn ará abúlé tí kìnìún wà láti má a fojú sọ́rí

Awọ̀n kiniun to duro Image copyright Reuters

Awọn kiniun mẹrinla ni wọn ti sa kuro ni ahamọ wọn ni ọgba ẹranko Kruger, to wa ni orilẹede South Africa.

Iroyin ti awọn alasẹ ọgba ẹwọn naa fisita sọ pe abule Phalaborwa, ti awọn awakusa pọ si julọ, ni wọn ti kofiri awọn kiniun naa, ti wọn n yan kiri.

Wọn ti wa sin awọn ara ilu naa ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn maa foju sọri, titi ti ọwọ awọn alasẹ yoo fi tẹ awọn kiniun ọhun.Èèmọ̀ wọ̀lú! Kìnìún mẹ́rìnlá bọ́ sígboro

Bẹẹ si ni awọn asọgbo to wa ni ọgba ẹranko Kruger, ti n sọ irinsi awọn kiniun naa, ki wọn ma baa seara abule ti wọn sa si lese.

Igba akọkọ kọ ree tawọn kiniun naa yoo sa kuro ni ahamọ wọn. Bẹẹ ni wọn se lọdun meji sẹyin nigba ti kiniun marun sa kuro ni ọgba ẹranko naa, amọ wọn ri wọn he pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Bi o tilẹ jẹ pe, wọn mọ odi yi ọgba ẹranko ọhun ka bo se yẹ, amọ awọn alasẹ ibẹ ni ko tii ye awọn ọna tawọn ẹranko naa n gba sa bọ sita.