Adewale Ayuba: Ogun ń ja àgbo Fújì, ni wọ́n ṣe ń jà

Adewale Ayuba Image copyright @officialayuba

Ilumọọka olorin Fuji, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko, Ọmọwe Adewale Ayuba ti woye pe, ogun lo n ja awọn olorin to wa ni agbo ile Fuji lo sokunfa ede aiyede ati ariyanjiyan to n waye lori ẹni to da orin Fuji silẹ atawọn aawọ miran.

Adewale Ayuba, lasiko to n kopa lori akanse eto ileesẹ wa BBC Yoruba, salaye pe ẹni ta ba laba, ni baba, lọrọ awọn to da orin Fuji silẹ, tii se Sikiru Ayinde Barrister ati Ayinla Kollington, ko si si ọrọ ansiyemeji nipa wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ wo fídíò to ti sọrọ naa lori akanse eto BBC Yoruba nibi:

O fikun pe bi awọn olorin to n kọ Fuji se n lo ohun to kẹ bii tawọn ọmọ isọta, ko sọ pe ọmọ buruku ni wọn, amọ ohun ti wọn fi n sọrọ tabi kọrin lo mu kawọn eeyan maa fi wọn we ọmọ onimọto.

Nigba to n dahun ibeere lori boya lootọ lo ti di ẹlẹsin Kristi, Ayuba ni lootọ ni oun jẹ Musulumi, amọ oun ko mọ keu ka, awọn Aafa ni oun maa n pe lati wa gbadura fun oun, ti oun si lọ sin Ọlọrun ni ilu Mecca.

Sugbọn Ayuba ni o rọrun fun oun lati ka bibeli lai ke si ẹnikẹni, ti bibeli funrarẹ si maa n fa oun, eyi to mu ki oun fara mọ ẹsin Kristiẹni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Nigba to n sọ pataki orin Fuji fun iran Yoruba, gbajugbaja olorin Bọnsue naa rọ ọmọ Yoruba kọọkan, lati tẹwọgba orin Fuji .

O ni nitori ara idamọ ti wọn mọ iran Yoruba mọ ni orin Fuji jẹ́, gẹgẹ bi wọn se mọ awọn orilẹede bii Jamaica, Amẹrika, India ati Brazil mọ irufẹ orin ti wọn n kọ ni ikọọkan awọn orilẹede yii.