Minimum wage: Àwọn gómìnà PDP láwọn yóò san #30,000 owó oṣù fáwọn òṣìṣẹ́

Seriake Dickson Image copyright Facecook/Seriake Dickson

Awọn gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn ti ṣetan lati san ọgbọn ẹgbẹrun un naira owo oṣu to kere julọ fawọn oṣiṣẹ.

Eleyi ni Aarẹ Muhammadu Buhari buwọ lu laipẹ yii.

Alaga awọn gomina PDP, Seriake Dickson ti ipinlẹ Bayelsa lo sọrọ naa fawọn akọroyin l'Abuja lọjọ Ẹti.

Dickson ṣalaye pe awọn ti gba lati sanwo naa lati din iṣẹ ku laarin awọn oṣiṣẹ lawọn ipinlẹ ti ẹgbẹ osẹlu PDP ti wọ le.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Gomina ipinlẹ Bayelsa ni asiko mti to lati ṣe ẹkunwo gidi fawọn oṣiṣẹ nitori ọjọ ti pẹ ti wọn n ti n gba owo kekere.

Ọgbẹni Dickson fikun ọrọ rẹ pe o ṣe pataki lati san ọgbọn ẹgbẹrun un nairia owo oṣu to kere julọ fawọn oṣiṣẹ nitori ọrọ aje Naijiria to dẹnu ko lẹ labẹ ijọba ẹgbẹ oṣelu APC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Gomina Bayelsa tun sọ pe ko si gomina PDP to lọwọ ninu nina owo ijọba ibilẹ tabi fifi ṣe nnkan miran.

O kepe ijọba apapọ lati fi orukọ awọn gomina to n dari owo ijọba ibilẹ si ibo miiran.