Sanwo-Olu: Àtàrí Àjànàkú ni àkóso Eko, kì í ṣe ẹrù ọmọdé

Gomina Ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu Image copyright Babajide Sanwoolu/Twitter

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti figbe ta pe, oun ti ru laarin ọsẹ kan ṣoṣo ti wọn bura fun oun, gẹgẹ bi gomina.

Sanwo-Olu ni o si jọ bi ẹni wipe oun yoo ṣi tun ru si lori ohun ti oju oun n ri gẹgẹbi ẹni to n tukọ Eko.

Àwọn ìròyìn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

O ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade kan to ṣe pẹlu Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo, saaju ipade naa si ni gbogbo awọn gomina nilẹ wa ti ṣe ipade pọ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari ni Abuja.

Sanwo-Olu ni didari Ipinlẹ Eko kii ṣe ere ọmọde nitori atari ajanaku ni, kii ṣe ẹru ọmọde.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters

Gomina Sanwo-Olu ni oun ko le e sun, ki oun ji pẹlu ero wipe wahala sunkẹrẹ-fakẹẹrẹ ọkọ yoo ti dopin, bẹẹ si ni oun ko le e sun, ki oun ji pẹlu ireti wipe ọrọ sunkẹrẹ-fakẹẹrẹ Apapa yoo ti poora.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Gomina ipinlẹ Eko ni oun ti awọn ara Eko fẹ ni pe, ki awọn ri amusẹ awọn ohun ti oun ti ṣe ileri fun wọn.

O tun rọ gbogbo awọn olugbe Ipinlẹ Eko lati gbaruku ti oun, ki iṣẹ ilu baa le tẹsiwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAjayi: ṣé ìwọ mọ irúfẹ́ ọmọ tí Yorùbá ń pè bẹ́ẹ̀?