#Sweetsweetcodeine: Ẹ wo bí ìròyìn BBC nípa oògùn ikọ́ Codeine ṣe ń tún ayé tó ti bàjẹ́ ṣe
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

BBC Africa Eye: Àṣìlò òògùn láàrín àwọn ìgbèríko ti ń dínkù

Ohun tẹ́ẹ̀ mọ̀ àti tí ẹ tí wá mọ̀ báyìí nípa ìjàmbá Codeine, báyìí ló ṣe bẹ̀rẹ̀.

Wakati mẹrinlelogun pere lẹyin ti akanṣe Ọ̀rọ̀ ń bọ́ lóríi fídíò Codeine iroyin ọtẹlẹmuyẹ BBC yii jade nipa bi ọja okunkun tita oogun ikọ olomi Codeine ṣe n gberu sii ni Naijiria ni ijọba gbera lati wa wọrọkọ fi ṣ'ada.

Bi oogun naa ṣe n ba aye awọn awọn eniyan j kọja afẹnusọ kaakiri orilẹede Naijiria leyii ti ko mọ olowo tabi talaka, ọmọde tabi agba, ọkunrin tabi obinrin to fi mọ awọn ẹlẹsin gan.

O fẹrẹẹ ma si ìpínlẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n o kii n mu oogun yii to bẹẹ ti a lee bẹrẹ si ni gbe e lẹgbẹ kẹgbẹ pe ipinlẹ bayii lo gba ipo ikinni ninu mimu oògùn Codeine jù. Koda, àwọn ìlú Yorùbá gan o gbẹyin ninu idije ta lo n mu oogun Codeine yii.

Africa Eye, ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ile iṣẹ BBC lo ṣe iṣẹ takun takun yii lati tu aṣiri ohun to fara sin to n ba aye ọpọlọpọ jẹ ni Naijiria.

Pẹlu owo pinisin ti wọn n ta igo kan,Codeine le di baraku fun eniyan tabi ko buru to bẹẹ ti yoo ṣe akoba fun agọ ara tabi ya eniyan ni were.

Inu igo ọti ẹlẹrindodo ni awọn mii a rọ ọ si ti ẹ o ni mọ

Koda awọn ileeṣẹ to ni ontẹ ijọba lo n ta a. Bawo wa ni o ṣe jẹ pe ojọba faaye gba a?

Aṣe awọn oṣiṣẹ ijọba kan tun wa to n lo aṣẹ ọba lati fòntẹ̀ jan ki awọn alagbata maa ta ogun yii lọna aitọ.

Ṣe bi owo ku lawọn oṣiṣẹ ijọba ọhun yoo gba

Wọ́n léè ta mílíọ̀nù kan páálí láàrín ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo!