June 12: Ọjọ́ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà, èdè àti ẹlẹ́sìnjẹ̀sìn tó wà ní Nàíjíríà papọ̀ di ọ̀kan

Oloye Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla Image copyright @mko_abiola

Ọjọ nla, ọjọ manigbagbe ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993, ti gbogbo eeyan mọ si June 12 jẹ ninu itan orilẹede Naijiria.

Ta a ba si n sọrọ nipa eto ijọba alagbada lorilẹede Naijria, a ko lee kọ iyan eto iselu naa, ka ma fi ewe bo ayajọ June 12 nitori ọpọ isẹlẹ kayeefi to waye lasiko naa ati ẹkọ to kọ orilẹede Naijiria.

Ọdun 1993 yii ni aarẹ ologun, Ibrahim Badamọsi Babangida wa lori aleefa, ti gbogbo ọmọ Naijiria si n ke boosi fun agbekalẹ ijọba alagbada lẹyin ti Babangida ti lo ọdun mẹjọ lori aleefa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'

Ki lo bi iṣẹlẹ June 12

Ijagudu awọn ọmọ Naijiria fun isejọba tiwa n tiwa lo mu ki Ibrahim Babangida fi se agbekalẹ ẹgbẹ oṣelu meji, eyiun ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, ti ami idamọ rẹ jẹ Ẹṣin, ti ọpọ eeyan si mọ si ẹgbẹ oselu ẹlẹṣin.

Ẹgbẹ oṣelu keji ni ẹgbẹ National Republican Convention, NRC, eyi ti ami idamọ rẹ jẹ Ẹyẹ, tawọn eeyan si mọ si ẹgbẹ ẹlẹyẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji yii lo ṣeto idibo abẹnu ti wọn si fa oludije fun ipo aarẹ kalẹ lati gbe asia ẹgbẹ oṣelu koowa wọn.

Oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu SDP ni Oloye Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla, ti gbogbo eeyan mọ si MKO Abiọla, nigbati igbakeji rẹ jẹ Alhaji Babagana Kingibe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun
Image copyright @General_Ibbro

Alatako fun ipo aarẹ latinu ẹgbẹ oṣelu NRC ni Bashir Tofa, ẹni to jẹ ọdọmọde, to si wa lati ẹkun ariwa orilẹede yii, nigbati igbakeji rẹ jẹ Sylvester Ugoh.

Oloye Abiọla ni tiẹ jẹ olowo, olokiki, gbajumọ, oloju aanu ati onisowo to ni ileesẹ nla-nla, ti awọn eeyan mọ bii isana ẹlẹẹta, nitori oju aanu to maa n se yika awọn ẹkun idibo to wa ni Naijiria, ko tiẹ to di pe o pinnu lati gbe igba ibo aarẹ rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWọle Ṣoyinka: Owe maa n ran mi leti MKO Abiọla

Lọna ati fi opin si aṣa ṣiṣe mọkaruru esi ibo, eyi to wọpọ ni Naijiria latẹyinwa, lo mu ki Ọgagun Babangida se agbekalẹ ilana eto idibo gbangba laṣa n ta, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Option A4.

Eto ilana idibo yii ni yoo fun awọn araalu ati oludibo ni agọ idibo kọọkan ni anfaani lati to si ẹyin aworan oludije fun ipo aarẹ to ba wu wọn.

Image copyright @MuhammadSageer

Lẹyin eyi ni awọn osisẹ ajọ eleto idibo to wa nikalẹ yoo si ka iye oludibo to to si ẹyin aworan naa, eyi ti yoo kọ silẹ bii esi idibo, tawọn asoju ẹgbẹ oselu kọọkan yoo si buwọlu, lati gba esi ibo naa wọle.

Ni ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 ti ibo naa waye, ilana gbangba laṣa n ta yii jẹ ki eto ibo naa lọ geerege, ti awọn eeyan si dibo fun oludije to wọn lai fi ti ẹya, ẹsin ati ede ṣe.

Sé o ti rí ère MKO Abiola tuntun?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé tó yẹ kí Abiọla gbé, àwọn wo ló ń gbé níbẹ̀?

Amọ o se ni laanu pe, wọn ka ibo naa de idaji, ni ijọba ologun nigba naa lọhun lai ni idi kan pato kede pe, wọn ko gbọdọ ka esi ibo naa mọ.

Ṣugbọn ninu idaji esi ibo ti wọn ka, Oloye MKO Abiọla lo n leke, ti awọn eeyan si gba pe oun lo jawe olubori ninu ibo naa, nitori oun lo ni ibo to pọ julọ.

Image copyright @mko_abiola

Oniruuru iporogan, ifẹhonu han, wahala, rogbodiyan ati jagidi-jagan si lo tẹle bi wọn se wọgile esi ibo aarẹ ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 naa.

Awọn eeyan si faake kọri pe ajọ eleto idibo, ti Humprey Nwosu lewaju rẹ, gbọdọ kede MKO Abiọla gẹgẹ bii ẹni to bori ibo aarẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ará ìlú Abiola ní Abẹokuta bá BBC sọ̀rọ̀

Ọpọ wahala to suyọ yii lo mu ki Ọgagun Ibrahim Babangida yẹba lori aleefa, ti Ọgagun Sani Abacha si gba ipo rẹ.

Ṣugbọn kaka ki ewe agbọn dẹ lori ọrọ ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993, ko ko ko lo tun n le si, ti rogbodiyan si tun suyọ lasiko ti wọn n ṣami ayajọ ọdun kan ti idibo naa waye.

Image copyright @mko_abiola

MKO Abiọla kede ara rẹ bii aarẹ fun Naijiria, ti wọn si sọ ọ si ahamọ. Rogbodiyan yii maa n waye ni ọdọọdun, titi ti ọgagun Abacha fi tẹri gbasọ lojiji, ti MKO Abiọla naa si tẹle.

Ọgagun Abdulsalami Abubakar di olori ijọba ologun ni Naijiria, to si ṣeto idibo aarẹ miran, eyi to gbe oloye Olusẹgun Ọbasanjọ wọle bii aarẹ orilẹede Naijiria.

Aarẹ ọna kakanfo Yoruba

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌdalẹ ni Babangida ati Abacha - Ọmọ Abiola

Ohun to mu ki ayajọ June 12 ṣe pataki fun Naijiria:

 • Ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 lo tii lọ ni irọwọ-rọsẹ ju lọ, laisi rogbodiyan lasiko ibo naa, gẹgẹ bo se maa n waye lasiko eto idibo nilẹ wa Naijiria
 • Oludije fun ibo aarẹ fẹgbẹ oselu SDP ti ọpọ eeyan gba pe oun lo bori ninu ibo naa, Oloye MKO Abiọla ati igbakeji rẹ, Babagana Kingibe ni wọn jọ jẹ ẹlẹsin musulumi, eyi ti ko sẹlẹ ri ninu itan oselu Naijiria
 • Ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 yii lawọn eeyan gba pe ko ni magomago ninu rara, to si jẹ ibo to tii ja gaara julọ ninu itan idibo Naijiria.
 • Gbogbo awujọ eeyan, ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati onwoye ibo labẹle ati loke okun lo panupọ kede ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 gẹgẹ bii eyi ti wọn faramọ julọ lai si atako kankan bi eyi to n waye lasiko yii.
 • Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
 • 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
 • Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
 • Ẹfunroye Tinubu - Ògbóǹtagí oníṣòwò, olówò ẹrú àti afọbajẹ
 • Samuel Ajayi Crowther, òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé èdè Yoruba lárugẹ
 • Fun igba akọkọ ninu itan oṣelu Naijiria, awọn eeyan dibo fun ẹni ti ọkan wọn fẹ lati ṣe aarẹ le wọn lori, lai fi ti ẹsin, ẹya ati ede ti wọn n sọ lẹnu ṣe, ti wọn si kẹyin si aṣa ẹlẹyamẹya, ẹlẹsinjẹsin ati ẹlẹkunjẹkun ti wọn maa n ṣe lasiko ibo, gẹgẹ baa ṣe n ri i lonii.
 • Fun igba akọkọ, ko si akọsilẹ ija, wahala, iwa ipa, ibo yiyi idunkooko mọni, jiji apoti ibo gbe, rogbodiyan ati laasigbo rara lasiko eto ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993, eyi to yatọ si ohun to n sẹlẹ lasiko taa wa yii
 • Igba akọkọ ree tawọn ọmọ Naijiria yoo dibo, ti wọn ko ni kede ẹni to wọle bii aarẹ ninu eto idibo naa
 • Eto ibo ọjọ Kejila osu Kẹfa ọdun 1993 lo sọ Oloye MKO Abisla di akọni ijọba awa ara wa, ti orukọ rẹ si di manigbagbe ninu eto oselu lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: