9th Assembly: PDP ní láìpẹ́ làwọn aráàlú yóò mọ ìyàtọ̀ lórí àkóso ilé aṣòfin

Ami idamọ ẹgbẹ iselu PDP Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oselu alatako gboogi ni Naijiria, PDP, ti fesi lori bi idibo ile asofin agba ilẹ wa se lọ ni ọjọ Isẹgun.

Gẹgẹ bi PDP ti wi, o ni awọn n fọwọ lẹran maa woye ohun ti yoo jẹ atubọtan ẹgbẹ oselu APC ati isejọba rẹ, nibayii ti akoso ile asofin agba ti bọ sọwọ wọn gẹgẹ bi wọn se n poungbẹ rẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, igbakeji akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede yii, Ọgbẹni Diran Ọdẹyẹmi ni laipẹ lai jinna ni awọn araalu funra wọn yoo mọ iyatọ laarin akoko ti ẹgbẹ oselu PDP n se akoso ile asofin apapọ ilẹ wa ati akoko ti APC n dari rẹ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdẹyẹmi ni lootọ ni kii se gbogbo igba lo yẹ ki awọn asofin maa tako ifẹ inu aarẹ ati ẹgbẹ oselu rẹ.

Amọ ko bojumu to ki awọn asofin sọ ara wọn di abẹsinkawọ fun aarẹ, ki wọn si ma ni ọkan akin lati yẹ ohun to ba n se, ti ko dara wo.

Image copyright @nassnigeria

Nigba to n ki aarẹ ile asofin agba tuntun ati igbakeji rẹ ku oriire ipo tuntun to ja mọ wọn lọwọ naa, ẹgbẹ PDP wa gba wọn nimọran lati mase lọ nipa ilana ẹlẹgbẹ oselu de, amọ ki wọn fi ifẹ ati idagbasoke Naijiria si ookan aya wọn, lasiko ti wọn ba n sisẹ ti ofin gbe le wọn lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Ọdẹyẹmi, lasiko to n sọrọ lori bi awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP kan se pọn lẹyin Ahmed Lawan dipo Alli Ndume, ti ẹgbẹ PDP fẹ lati se atilẹyin fun lasiko idibo naa, igbakeji akọwe ipolongo fẹgbẹ PDP ni, ko si ohun to buru ninu ohun ti awọn asofin PDP naa se nitori o pẹ diẹ ki ẹgbẹ PDP gan to sọ ẹni ti wọn yoo dibo fun, fun wọn.