June 12: Buhari fi orúkọ Abiola sọ pápá ìṣeré l'Abuja

Aarẹ Muhammadu Buhari kede pe papa iṣere ijọba apapọ to wa l'Abuja yoo maa jẹ Moshood Olawale Abiola Stadium bayii.

Aarẹ Buhari sọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to sọ nibi ayajọ ọjọ ijọba awarawa akọkọ iru rẹ l'Abuja lonii.

Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari

Aarẹ Buhari ni ipa ti Abiola ati igbakeji rẹ, Baba Gana Kinjibe ti wọn jọ gbegba ibo lọdun 1993 kii ṣe kekere ninu eto oṣelu orilẹede Naijiria.

Ọpọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan lo ti n sọ fun ijọba apapọ lati fi orukọ Abiola sọ nnkan kan to jẹ ti ijọba apapọ ko le jẹ iranti nitori pa rẹ ninu eto oṣelu Naijiria.

Aarẹ Buhari tun sọ pe ijọba oun yoo gbiyanju lati yọ ọpọ ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ ati oṣi to n ba ọpọ eeyan finra.

Aarẹ sọ pe orilẹede Naijiria lagbara lati yọ ọgọrun miliọnu ọmọ Nigeria ninu iṣẹ laarin ọdun mẹwaa.

Aarẹ Buhari tun fikun ọrọ pe ijọba oun yoo tubọ ṣiṣẹ takuntakun si lati rii wi pe eto aabo mọnyan lori, ati pe ijọba tun ọrọ aje Naijiria ṣe sii.

Aarẹ tun sọ pe ijọba oun ko ni foju re wo ẹnikẹni to ba fẹ da rogbodiyan silẹ nibi kibi kaakiri orilẹede Naijria ati awọn to ba kowo ilu jẹ.

Aarẹ Naijiria sọ pe laarin ọdun mẹrin saa keji ijọba oun, oun yoo jẹ ki ina mọnamọna wa lowo pọọku fawọn ọmọ Naijiria.

Ilu Abuja rosomu

Ilu Abuja rosomu fun ayajọ ijọba awa ara wa eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣẹṣẹ buwọlu pe ko maa waye ni gbogbo jọkejila oṣu kẹfa dun latoni lọ.

Kẹti kẹti ni ero n tu ni gbagede Eagle Square ni olu ilu orilẹede yii, Abuja nibi ti eto naa ti n waye.

Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari

Ṣaaju ọdun 2019, ọj ikọkandinlọgbn oṣu ikarun un ni orilẹede Naijiria maa n yẹ si tẹlẹ gẹgẹ bi ayajọ ijọba awa ara wa.

Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun un ọdun 2019 ni aarẹ Buhari ṣẹṣẹ buwọlu u pe June 12 ti kii ṣe ajoji si gbogbo ọmọ Naijiria ni wọn yoo maa ṣe ayajọ ijọba awa ara wa ni Naijiria.

Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari

Pataki rẹ julọ fun iran Yoruba ati awọn ọmọ Naijiria lapapọ to ṣi ranti iṣẹlẹ ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 1993 ni pe ọjọ naa lọhun ni ti ibo waye ni NAijiria.

Ilana idibo gbangba laṣa n ta yii jẹ ki eto ibo naa lọ geerege, ti awọn eeyan si dibo fun oludije to wọn lai fi ti ẹya, ẹsin ati ede ṣe.

Agbára wo ni June 12 fún MKO Abiola tó ṣì ń fọhùn lẹ́yìn ikú rẹ̀?

Sé o ti rí ère MKO Abiola tuntun?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé tó yẹ kí Abiọla gbé, àwọn wo ló ń gbé níbẹ̀?

Wọn ka ibo naa de idaji, ni ijọba ologun nigba naa lọhun lai ni idi kan pato kede pe, wọn ko gbọdọ ka esi ibo naa mọ.

Ṣugbọn ninu idaji esi ibo ti wọn ka, Oloye MKO Abiọla lo n leke, ti awọn eeyan si gba pe oun lo jawe olubori ninu ibo naa, nitori oun lo ni ibo to pọ julọ.

Eyi jẹ diẹ ninu itan to mu ki June 12 ṣe pataki fun iran Yoruba.