MKO Abiola: Ọmọ 23 ni bàbá MKO Abiọla bí saájú rẹ̀, àmọ́ òun ni àkọ́bí

Oloye Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla Image copyright @mko_abiola

Ti a ba n sọrọ awọn ọlọla, olowo, ọlọrọ, oloselu, ẹlẹyinju aanu ati onisowo pataki lorilẹede Naijiria, o loju ẹni to lee bọ sita pe oun siwaju Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla, ti gbogbo eeyan mọ si MKO Abiọla.

Idi ni pe ọpọ ipa ribiribi ni MKO Abiọla ko si ẹka oselu, okoowo, aanu sise, agbega ọrọ aje ati ipese awọn ohun eelo amayedẹrun yika tibu tooro Naijiria.

Ni igba aye rẹ, ọpọ eeyan lo tumọ orukọ MKO si Money, Kudi, Owo, eyi to jẹ owo apekanuko lede Yoruba. Idi ni pe MKO Abiọla ri taje se, Ọlọrun bẹ igi ọla fun, to si jẹ ilumọọka kaakiri agbaye nitori buruji to ni, to si n ṣe aanu fun awọn mẹkunnu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iwa aanu rẹ yii si lo mu ki ọpọ eeyan jade lati dibo fun pe ko di aarẹ Naijiria lọjọ Kejila, osu Kẹfa ọdun 1993, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko kede rẹ bii aarẹ, eyi to fa rogbodiyan ni Naijiria, to si tun da ẹmi MKO Abiọla legbodo, amọ ti awọn eeyan n seranti rẹ titi di oni oloni.

Image copyright @mko_abiola

Bi onirese MKO Abiọla ko ba wa fin igba mọ, eyi to ti fin ko lee parun laelae, idi si ree to fi yẹ ka mọ nkan kan, abi meji nipa igbe aye oloore yii, gẹgẹ ba ṣe ka loju opo itakun agbaye Wikipedia, ẹni to fi ẹmi rẹ lelẹ fun ifẹsẹmulẹ ijọba alagbada ati idagbasoke orilẹede Naijiria.

Itan igbe aye MKO Abiọla:

 • Ọjọ Kẹrinlelogun osu Kẹjọ ọdun 1937 ni Salawu ati Wuraọla Abisla bi Moshood sile aye lẹyin ti wọn ti bi ọpọ ọmọ to to mẹtalelogun sẹyin, ti ireti wọn si ti dinku pe o seese ki ọmọ tuntun naa ye
 • Idi ree ti wọn fi kọkọ pe ni orukọ rẹ ni Kasimawo, nitori pe wọn lero pe oun naa lee gbọna ọrun lọ bii awọn ọmọ to siwaju rẹ. O si to ọdun mẹẹdogun ti wọn ti bi sile aye, ki wọn to sọ ni suna Moshood. Eyi to mu ko jẹ akọbi awọn obi rẹ.
 • Agbẹ onikoko parau ni baba MKO Abiọla, ti iya rẹ si n ta obi, to si maa n ran baba rẹ lọwọ ninu isẹ naa, amọ lọdun 1946, nkan dakun, nigba tawọn eebo to n ra koko ni koko ti baba rẹ gbin ko dara, ki wọn lọ jo nina ni, isẹlẹ yii si lo ran baba naa sọrun ni aipe ọjọ
Image copyright @mko_abiola

Eto ẹkọ MKO Abiọla:

 • Ọmọ ọdun mẹsan ni Moshood wa to fi n sẹ igi ta ni owurọ kutukutu ko to lọ sile iwe nitori ati jẹnu, eyi si la lee pe ni okoowo akọkọ ti yoo dawọ le ni kutukutu aye rẹ, ileẹkọ alakọbẹrẹ African central school, si lo kọkọ ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ
 • Nigba to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun, Moshood da ẹgbẹ olorin kan silẹ, ti wọn yoo kọ orin fawọn alejo lasiko ayẹyẹ, ọna lati ri ounjẹ oojọ jẹ ni, wọn kii si fun wọn ni owo afi ounjẹ. Ams nigba to ya, o bẹrẹ si gba owo fun isẹ orin kikọ, eyi to fi n bọ ẹbi rẹ, to si tun n ran ara rẹ ni ile ẹkọ girama ni Baptist Boys High school, Abẹokuta
 • Nigba ti wọn wa nile ẹkọ girama yii, ọpọ awọn eeyan jankan jankan lawujọ loni ni o jẹ ọmọ ileẹkọ MKO Abiọla nigba naa, ninu wọn la ti ri Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ, to jẹ aarẹ tẹlẹ ni Naijiria. Nigba ti MKO Abiọla jẹ olootu iwe iroyin atigbadegba kan 'The Trumpeter' nileewe, Olusẹgun Ọbasanjọ ni igbakeji rẹ
 • Ọdun 1956 ni MKO Abiọla bẹrẹ isẹ bii akọwe nile ifowopamọ Barclays nilu Ibadan amọ lọdun 1960 lo ri ẹkọ ọfẹ gba lati lọ kawe loke okun ni fasiti Glasgow, nibi to ti gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ nipa isiro owo, to si tun kawe di akọsẹmọsẹ olusiro owo
 • Ni kete to pada de si Naijiria, ni Moshood bẹrẹ isẹ pẹlu ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti Eko gẹgẹ bii olusiro owo agba, ko to tun lọ sile isẹ apoogun Pfizer, lẹyin naa lo tun dara pọ mọ ileesẹ to wa fun eto ibaraẹnisọrọ, ITT, nibi to ti di igbakeji aarẹ fun ẹkun Afirika ati aarin gbungbun agbaye, Middle East
 • Nigba to se diẹ, MKO Abiọla di olokoowo aladani, to si n da ileesẹ ara rẹ silẹ ni oniruuru ẹka. O da oko ọgbin Abiọla farms silẹ, ibudo itawe Abiola Bookshops, ileesẹ ti wọn ti n ta eroja fun agbekalẹ ileesẹ redio, ileesẹ burẹdi Wonder bakeries, ileesẹ iroyin Concord Press, ileesẹ ofurufu Concord Airlines, ileesẹ elepo Summit oil, ileesẹ ọkọ oju omi Africa Ocean Lines, ile ifowopamọ Habib, ileesẹ to n gbe awo orin jade Decca W.A Ltd, ẹgbẹ agbabọọlu Abiọla Football club ati bẹẹbẹẹ lọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌdalẹ ni Babangida ati Abacha - Ọmọ Abiola

MKO Abiọla gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu, baale ile ati olori ẹsin:

 • Bi MKO Abiọla se jẹ ọlọrọ to yii, Ọba oke fi omi aanu si oju rẹ, ọpọ eeyan to ba si ba ẹkun wọ inu ile abi ọọfisi rẹ lo maa n ba ẹrin jade, nitori oun gan la ba maa pe olowo to n fi owo saanu, ti kii si fẹ ri omije loju mẹkunnu rara
 • Idi ree ti ọpọ agbegbe, ilu, ileto,ẹya ati orilẹede fi n fi oye jankanjankan da Abiọla lọla nigba aye rẹ, a si gbọ pe oye to jẹ le ni igba, to ko tẹri gbasọ. Lati ọdun 1972 titi di igba to jẹ alaisi, lo ti jẹ oye toto mẹtadinnigba lati ilu mejildinlaadọrin yika Naijiria. Amọ eyi to fẹran julọ ni oye Basọrun ati Aarẹ Ọna Kakanfo.
 • O kọ ile ẹkọ girama mẹtalelọgọta, Mọsalasi ati Sọọsi mọkanlelọgọfa, ibudo iyawekawe mọkanlelogun, ipese ibudo omi mimu mẹrinlelogun yika naijiria, to si tun jẹ baba isalẹ fun ẹlẹgbẹjẹgbẹ mọkandinlaadọjọ
 • MKO Abiọla jẹ alagbo nla, o ni ọpọ iyawo, to si bi ọmọ pupọ. Simbiat Atinukẹ Soaga ni iyale rẹ, ọdun 1960 si lo ba segbeyawo, ko to fẹ Kudirat Ọlayinka Adeyẹmi tẹle lọdun 1973, lẹyin naa lo fẹ Adebisi Ọlawunmi Ọshin lọdun 1974 ati Doyinsọla Abọaba lọdun 1981.
 • Awọn yoku ni Modupẹ Onitiri ati Rẹmi Abiọla.

Irinajo MKO Abiọla ninu oṣelu:

 • Ọmọ ti yoo ba jẹ aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samusamu ni ọrọ MKO Abiọla ninu oselu nitori ẹni ọdun mọkandinlogun lo wa, to fi darapọ mọ oselu sise, ẹgbẹ oselu NCNC si lo darapọ mọ nigba naa, ko to lọ pari ẹkọ rẹ. Nigba to tun pada sidi oselu lọdun 1980, lo di alaga ẹgbẹ oselu NPN, ti ireti si wa pe yoo dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria lẹyin saa keji aarẹ to wa nipo, ko to di pe awọn ologun ditẹ gba ijọba lọdun 1983
 • Lẹyin ọdun mẹwa tawọn ologun ti n dari Naijiria, wọn se agbekalẹ ẹgbẹ oselu alagbada meji fun ipadapọ ijọba tiwantiwa, ti MKO Abiọla si darapọ mọ ẹgbẹ oselu Ẹlẹsin taa mọ si Social Democratic Party, SDP, nibi to ti gbe apoti fun ibo aarẹ lọdun 1993
 • Gbogbo eeyan lo tu yaya jade lati di bio MKO Abiọla lọjọ Kejila, osu Kẹfa ọdun 1993, eyi ta mọ si June 12, ti ireti si wa pe oun lo moke ninu ibo naa bi o tilẹ jẹ pe idaji esi ibo naa ni wọn ka, ki wọn to dawọ duro, eyi to mu laasigbo ba orilẹede yii
 • Lasiko ti MKO Abiọla wa lọgba ẹwọn yii, ni wọn yinbọn pa ọkan lara iyawo rẹ, Kudirat Abiọla nilu Eko lọdun 1996 nitori pe o n se atilẹyin fun ọkọ rẹ to ti lo kọja ọdun marun ninu ahamọ
 • MKO Abiọla kede ara rẹ bii aarẹ Naijiria lẹyin ọdun kan ti eto idibo June 12 waye, ti ijọba ologun Sani Abacha si sọ si ahamọ, nibi to wa to fi jalaisi lọjọ Keje osu Keje ọdun 1998

Yooba ni baa ku laa dere, eeyan ko sunwọn ni aaye, wọn fi oye igbẹyin da MKO Abiọla lọla lẹyin ogun ọdun to ti tẹri gbasọ, nigba ti aarẹ Muhammadu Buhari fi oye GCFR da lọla lọdun 2018, oye yii si ni wọn maa n fun ọwọ awọn eeyan to jẹ adari lorilẹede Naijiria.