Lagos/Ibadan Expressway: Èèyàn mẹ́jọ ló kù nínú ìjàmbá ọkọ̀ kìí ṣé mẹ́ẹ̀dógún

Aworan ijamba ọkọ
Àkọlé àwòrán Lagos/Ibadan Expressway: Ọpọ̀ èrò ló farapa tí mọ́tò ṣòfò

Ọkunrin mẹfa,obinrin kan ati ọmọdekunrin kan lo ku ninu ijamba ọkọ to waye lopopona marose Eko si Ibadan.

Eeyan mejila si farapa.

Ajọ ẹsọ alabo oju popo lo sọ eyi di mimọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwero pẹlu olori ẹka wọn ni ipinlẹ Ogun,Clement Oladele.

Oladele salaye pe ere asapajude lo ṣokunfa iṣẹlẹ yi ti ọkọ meje si farakasa ijamba naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saaju ni awọn ti ọrọ naa soju wọn kan ti ni o to eeyan mẹẹdogun ti o ku ninu iṣẹlẹ yi.

Ijamba ọkọ naa la gbọ wi pe akọkọ rẹ ṣẹlẹ ni nnkan bi ago meje ọjọru ti awọn miran si tun ṣelẹ lowurọ ọjọbọ.

Lagbegbe kan ti wọn n pe ni Danko saaju ki a to de Sagamu ni o ti waye.

Isẹlẹ naa ti da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ ti awọn ẹsọ ajọ oju popo si n gbiyanju lati dari lilọ bibọ ọkọ.

Àkọlé àwòrán Lagbegbe kan ti wọn n pe ni Danko saaju ki a to de Sagamu ni o ti waye.

Akọroyin BBC Yoruba, Olu Alebiosu ti oun naa n rin loju ọna naa jabọ pe awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ pe ọkọ nla kan to ya si ibi ti ko yẹ lo mu ki ijamba naa sẹlẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti o sọ, O ni awọn alafojuri nibi iṣẹlẹ naa bi ọkọ naa ṣe ya lojiji lo mu ki awọn miran to n bọ lẹyin rẹ fori sọ ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu awọn ọkọ to farakasa la ti ri ọkọ akero kan to fi mọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ miran.

A ko ti ri aridaju lati ọdọ awọn ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lori iye eeyan to ku ṣugbọn awọn to wa nibẹ ni ko le kere ju mẹẹdogun lọ

Àkọlé àwòrán Ijamba ọkọ naa da sunkẹrẹ fakẹrẹ silẹ loju ọna naa

Akọroyin wa jabọ pe nisoju oun, awọn ẹsọ abo oju popo n fi ọkọ alaarẹ gbe awọn eeyan kan to farapa lọ si ile iwosan.

Ni kete ti a ba ti ni iroyin miran nipa iṣẹlẹ yi ni a o fi too yin leti.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption9th Assembly: Aráàlú ní àwọn ń fẹ́ ìpèsè àwọn ohun èèlò amáyédẹrùn