Ikú Dagunro: Sajẹ ní èèyàn tó ṣe gbáralé ni Dagunro, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dìde láti ara rẹ̀

Fasasi Ọlabankẹwin, ti gbogbo eeyan mọ si Dagunro. Image copyright Sajetiologa

Awọn agba ọjẹ ninu isẹ tiata ni ẹka ti Yoruba ti n sọrọ nipa gbajugbaja osere tiata, Fasasi Ọlabankẹwin, ti gbogbo eeyan mọ si Dagunro. to mi kanlẹ lowurọ Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi BBC Yoruba se gbọ, idaji ọjọbọ ni Dagunro mi kanlẹ nile rẹ nilu Eko lasiko aisan ranpẹ to ti n ba finra lati bii ọdun melo kan sẹyin, eyi ti a ko tii lee sọ iru aisan ti o jẹ.

Nigba to n sedaro Dagunro, Adebayọ Salami, ti a mọ si ọga Bello, se apejuwe Dagunro bii ẹni to gbe asa Yoruba ga ni nigba aye re.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oga Bello ni oninu ire ni Dagunro, to si ni itẹriba fun awọn asaaju ninu osere tiata nitori o ri oun gẹgẹ bi oga rẹ, to si bọwọ fun oun.

O fikun un wi pe iku rẹ dun oun, ati wi pe, agbo osere tiata Nollywood ko lee gbagbe rẹ mọ lai.

Bakan naa, gbajugbaja oserebinrin, Alhaja Fausat Balogun, ta a mọ si Madam Sajẹ, naa ti ni eniyan to se e gbarale ni Dagunro nigba aye rẹ.

Image copyright Sajetiologa

Saje ni ọpọlọpọ awọn olosere lo dide lati ara rẹ, ti gbogbo wọn si mọ Dagunro si ẹni to nifẹ si iserere awọn akẹgbẹ rẹ.

O fikun wi pe, ipa ribiribi ti Dagunro ko si ere tiata ni pe awọn eniyan ti ara rẹ dide, ti wọn si di olokiki eniyan.

Pẹlu idunnu ọkan ni Madam Saje fi sọ wi pe, awọn fẹran Dagunro, amọ Ọlọrun fẹran rẹ ju awọn lọ.

Lara awọn ere ti Dagunro ti se nigba aye rẹ ni Ija Abija, Dagunro, Jagunmolu, Ibinu Ọmọ Eleye, Abẹni Agbọn, Kakaki 'leku, Ikilọ agba ati Inu bibi.

Dagunro dagbere faye pe o digbose

Iku ti pa agbe, bii ẹni ti ko lee daro; iku ti pa aluko, bii ẹni ti ko lee kun osun; iku ti pa lekenleke, bii ẹni ti ko lee kun ẹfun.

Iku ti pa ojú ilumọọka agba osere kan de, Fasasi Ọlabankẹwin, ti gbogbo eeyan mọ si Dagunro Alakija oogun

Image copyright Sajetiologa

A gbọ pe irọlẹ ọjọbọ ni wọn yoo sinku agba osere to tẹri gbasọ naa ni ile rẹ ni Oṣogbo.

Dagunro lo maa n se ere to jẹ mọ ti asa ibilẹ, to si maa n se ere oloogun pẹlu ọfọ, oun si ni osere tiata keje ti yoo silẹ bora ninu awọn osere tiata Yoruba lọdun yii.

Ọmọkunrin meji ni Dagunro bi, awọn mejeeji naa si lo n se isẹ tiata. Orukọ wọn ni Kazeem Iyanda Olabankẹwin ati Jamiu Olabankẹwin.

Image copyright Sajetiologa

Wayi o, ọpọ awọn osere tiata lede Yoruba lo ti n sedaro akọni osere to lọ naa, ti ọpọ awọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye si ti kun fun idaro iku Dagunro.

Loju opo Instagram rẹ, Alhaja Fausat Balogun, ti gbogbo eeyan mọ si Sajẹtiologa naa ti kede iku gbajugbaja osere naa.

Ọba orin Saheed Osupa naa ti saaro Dagunro.

Bakan naa ni idaro yii ko yọ Sanyẹri silẹ.

BBC Yoruba naa wa n gbadura pe ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun Fasasi Ọlabankẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Dagunro.