First Lady: Kí ló mú Aisha Buhari gbà oyè tó kọ tẹlẹ?

Aworan apejẹ idupẹ Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari

Lati wakati yi lọ,'First Lady', eyi tii se obinrin akọkọ ni Naijiria, ni ki ẹ ma pe mi.

Ọrọ to n ja rainrain ree, eyi to jade lẹnu iyawo aarẹ Naijiria, Aisha Buhari.

Iyawo aarẹ lorileede Naijiria, Aisha Buhari ki i ṣe ẹni to n bẹru lati sọ ohun to wa lọkan rẹ.

Pupọ ninu awọn nkan to ba sọ lawọn eeyan ma n ran mọ ẹnu, to si maa n da awuyewuye silẹ nigba mi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aisha sọ ọrọ naa lọjọbo, ti oju opo Twitter si ti gbana jẹ lori rẹ.

Nibi apejẹ kan fawọn iyawo Gomina ti wọn ṣẹṣẹ yan, ati awọn ti ọkọ wọn pari saa wọn,ni aya aarẹ ti sọ ọrọ to nii ṣe pẹlu yiyi orukọ oye ara rẹ pada lati Wife of the President, iyawo aarẹ si First Lady, obinrin akọkọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Koda, o tun tọrọ aforijin pe oun sọ fun wọn saaju lati maa pe oun ni aya aarẹ dipo obinrin akọkọ ni Naijiria.

Kini o mu ipinnu tuntun Aisha yii wa?

Saaju ko to di pe Muhammadu Buhari, tii se ọkọ rẹ di aarẹ, ni Aisha Buhari ninu ifọrọwero kan pẹlu ile iṣẹ Iroyin TVC lọdun 2015 sọ pe, oun gbagbọ pe iyawo aarẹ ologun nigba kan ri, Mariam Babangida lo fi ipo First Lady lọlẹ.

Aya Buhari ni ''lati igba ti Mariam Babangida ti ku ni ipo yi ti wọmi, ni temi ti ọkọ mi ba wọle gẹgẹ bi aarẹ, mi o ni jẹ oye First Lady, bii kii ṣe ki wọn ma a pe mi ni iyawo aarẹ''

O si dabi ẹni pe ọrọ ọkọ rẹ to ni oun ko ni faye gba ipo First Lady labẹ ijọba oun, ni Aisha Buhari tẹle.

Image copyright George Okoro
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari ko ṣẹsẹ ma f'ọ̀rọ̀ da ìgboro rú lórí ìjọba ọkọ rẹ̀

Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Buhari sọ fun awọn akọroyin saaju ko to di aarẹ pe, iwe ofin ko faye gba ipo First Lady, fun idi eyi, oun ko ni fi aaye gba.

Fọdun mẹrin tọkọ rẹ fi ṣe ijọba, wọn ko pe Aisha Buhari ni First Lady, amọ aarẹ Buhari yan awọn amugbalẹgbẹ fun Aisha Buhari, ti iṣẹ wọn ko si fi bẹẹ yatọ si ki wọn ma ba First Lady ṣiṣẹ.

Iyipada tuntun yii, gẹgẹ bi Aisha Buhari ṣe sọ nibi apeje awọn iyawo Gomina, ko ṣẹyin ki iyemeji ma baa waye lori bi wọn yoo ṣe ma pe awọn iyawo Gomina tuntun, paapa julọ, awọn ti ọkọ wọn ba ni ju iyawo kan lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionafin pupa

Lọpọ igba, ti aarẹ ba ni ju iyawo kan lọ, iyale ninu awọn iyawo naa ni wọn ma n pe ni First Lady, ti awọn iyawo yoku yoo si maa jẹ iyawo aarẹ, wife of the President.

Irori Buhari ati Aisha ko papọ lọpọ igba

Ọrọ ti Aisha Buhari sọ yii kọ ni yoo jẹ igba akọkọ, ti ọrọ rẹ ati ti ọkọ rẹ yoo ma a tase ara wọn.

Ninu ọrọ akọroyin onwoye kan to ba BBC sọrọ, Abdulaziz Abdulaziz, o ni ọrọ yii ko ya oun lẹnu nitori pe, irori Aisha Buhari ati Buhari to jẹ ọkọ rẹ, kii papọ lọpọ igba.

Image copyright Aisha buhari

''A ko mọ ẹni ti yoo bori lọtẹ yi nipa ipo First Lady, nitori nnkan ti Aisha loun fẹ ree''

O salaye pe, ọrọ ọọfisi 'First Lady' ohun gan tẹlẹ dabi arumọjẹ nitori ''kii ṣe wi pe nnkan ti Aisha n ṣe gẹgẹ bi Iyawo aarẹ, Wife of the President, yatọ si nkan ti ẹni to jẹ 'First Lady' n ṣe''

Abdulaziz pari ọrọ rẹ pe ''orukọ lasan ni wọn fẹ yii pada, ko si iyatọ''