Kano Gorilla: Òṣìṣẹ́ 10 wọ gàù lórí ọ̀rọ̀ Ìnàkí tí wọ́n ló gbé owó tí wọn pa lásìkò ìtúnu ààwẹ̀

Gorilla dey chop Image copyright JOHN MACDOUGALL
Àkọlé àwòrán Ipinlẹ Kano Ìnàkí jí mílíọ̀nù méje náírà ní sgbà ẹranko

Ọjọ́rú ni ọ̀gá àgbà tó ń ṣe àkóso owó lọgba ẹranko ni Kano ké gbàjare pé, owó to ku díẹ̀ ko pé mílíọnù méje ti àwọn pa lásíkò ọdún itunu aawẹ, nígbà ti àwọ̀n ènìyàn wá wo ẹranko ló dédé pòòrá, nínú akoto ti àwọn ko owo si.

Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé BBC Yorùbá kò lè fìdí ọotọ mulẹ pe inaki mi owo náà, àmọ̀ awọn akọròyìn Freedom radio ní ìpínlẹ̀ Kano royìn lọ́jọ́bọ pé, ọkan nínú àwọn oṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka akoso owó ló sàlàyé pé, ìnàkí ńla kan lo wọ inú ọfíísì àwọn láti gbé owó náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbà ti BBC ba ọgá àgbà lọgba eranko náà sọ̀rọ̀, ó kọ̀ láti fí ìdí ọ̀rọ̀ yii múlẹ̀ yálà pé ó ṣẹlẹ̀ tàbí kò ṣẹlẹ̀, ó ni ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, òun kò si ní ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ le lóri.

" Ọ̀rọ̀ náà wa lábẹ́ ìwádìí, mí ò ṣetán láti sọ̀rọ̀ le lóri, ọ̀pọ̀ àwọn oníròyìn ló ti wá bá mi lórí ọ̀rọ̀ náà, ǹkan ti mo kàn le sọ ni pé owó sọnu" èyí ní ọ̀rọ̀ Kashekobo.

Ọkan nínú osiṣẹ ọgbà náà tó ní ki BBC má dá orúkọ oun sàlàyé pe, ọlọ́pàá ti mú gbogbo àwọn to wà lẹ́nu iṣẹ́ lásikò ti owó náà pòòrá

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Bákan náà ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kano, DSP Adbdullahi Haruna sàlàyé pé, ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lóri ọ̀rọ̀ náà.

"Òòtọ́ ní pé owó sọnu ní ilé ti wọ́n ń ko eranko si ní Kano, èyí to jẹ owó ti wọn pa ní ọ̀jọ́ márùn ti wọ́n fi ṣe ayẹyẹ ọdún ìtúnu ààwẹ. Ó ni bí oun ṣe ń sọrọ̀ yìí, àwọn oṣìṣẹ́ mẹ́wàá lo ti wà ní agọ́ ọlọ́pàá."

"Lára àwọn ti ọlọ́pàá mú ni ọlọdẹ àti àwọn to n siṣẹ́ ní eka owó, sùgbọ́n ǹkan ti a fẹ wadi ni pe, kí ni ìdí ti wọ́n fi kó owó pamọ si ọfíísi fún odidi ọjọ márùn láì ko lọ si ilé ìfowopamọ. Èyi ni ọ̀rọ̀ agbẹ́nusọ ọlọ́pàá.