Ọlọ́paà Ọ̀ṣun: Ààbò wà fún ẹ̀mí àti dúkìá aráàlú

Awọn ọlọ́pàá Image copyright @PoliceNG

Ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Osun ti mu awọn janduku mẹtala ti wọn n ṣọṣẹ ni awọn opopona to wa ni ipinlẹ naa.

Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun, Folasade Odoro rọ awọn ara ilu ninu atẹjade kan wipe, ki wọn ye gbe ahesọ ti ko fẹsẹ mulẹ sori ayelujara nipa bi ọrọ aabo ipinlẹ naa ṣe ri.

Ṣugbọn ọrọ rẹ yii kọ ẹyin si awọn iroyin to n ti ipinlẹ naa jade wipe, lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn awọn janduku oju popo ti pa awọn awakọ ati arinrinajo ni popona Ibadan si Ife, ati oju ona Iwaraja ni agbegbe Ilesa.

Iroyin naa ti lẹ ni wọn ji awọn eeyan miiran gbe.

Odoro sọ pe, Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa Abiodun Ige ti mu da awọn ara ilu loju wi pe, aabo wa fun ẹmi ati dukia wọn.

O ni awọn ọlọpaa mu awọn janduku naa, lẹyin ti wọn ya bo ibùba awọn janduku to wa ni awọn opopona to wa kaakiri ipinlẹ Osun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Agbẹnusọ naa ni, ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa yoo tubọ maa gbiyanju lati mu alaafia ati aabo duro ni ipinlẹ naa.