Apapa gridlock: Ìjọba àpapọ̀ ní òun kò ní gbà kí wọ́n ba ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yìí jẹ́

Awọn ọkọ akẹru to di oju ọna Apapa

Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo ti sun gbedeke igba to fun awọn awakọ tirela ti wọn wa loju ọna Apapa ni ọsẹ meji si, lati palẹ gbogbo ọkọ wọn mọ.

Aṣẹ ileeṣẹ aarẹ lori ọrọ naa ni oṣu kẹrin, lo dun mọ ọmọ Naijiria ninu. Ọsẹ meji pere ni wọn fun awọn ọlọkọ epo naa nigba naa, lati ko aasa wọn.

Ṣugbọn bi ijọba ṣe sun gbedeke ọsẹ meji yii siwaju fun ọsẹ meji miiran, n kọ ọmọ Naijiria lominu wipe, o seeṣe ki aṣẹ naa ma fẹsẹ mulẹ.

Atẹjade kan lati ileeṣẹ igbakeji aarẹ ni wọn buwọ lu, bi wọn ṣe sun gbedeke naa siwaju ninu ipade kan pẹlu awọn ti ọrọ kan ni ibẹrẹ ọsẹ yii.

Igbakeji aarẹ ni, wọn gbọdọ jabọ ni ọjọ Kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2019 bayii.

Aarẹ ni ijọba ko ni jẹ ki awọn kan fi imọtara ẹni ba ọrọ aje Naijiria jẹ nitori wipe, Apapa jẹ agbegbe gboogi ninu ọrọ aje Naijiria nitori ebute to wa nibẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn èèyàn àti awakọ̀ ké igbe ìrora bí àwọn ọkọ̀ ńlá ṣe dí ọ̀nà mọ́rosẹ̀ Apapa-Oshodi pa

Kayode Opeifa to jẹ igbakeji igbimọ amuṣẹṣe lori ọrọ naa ni, ijọba ti n gbe igbesẹ lati kọ awọn ibudokọ fun awọn ọkọ ajagbe to ba fẹ ko ẹru ni Apapa.

Related Topics