AD,LP, fìdírẹmii lórí ẹ́jọ́ tí wọn fí takò iyansipo Sanwo Olu

Aworan Gomina Eko Babajide Sanwoolu Image copyright @jidesanwoolu
Àkọlé àwòrán Sanwo Olu bori igbẹjọ iyansipo rẹ

Sanwo Olu ti bori ẹjọ ti AD ati LP pè.

Igbimọ igbẹjọ lori idibo Gomina ipinlẹ Eko ti fagile ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy, AD ati Labour Party, LP gbe wa siwaju rẹ.

Wọn mu ẹjọ yi wa ni itako iyansipo Gomina Babajide Sanwo Olu ti ẹgbẹ APC.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ, alaga igbimọ to n gbẹjọ naa T.T Asua wọgile ẹjọ naa tori pe awọn olupẹjọ kuna lati fi iwe ranṣẹ saaju gbendeke ọjọ meje ti ofin la kalẹ.

Igbimọ ẹlẹni mẹta naa ni titete kọ iwe yi jẹ opa kutẹlẹ pataki ninu pipe ẹjọ ati pe bi eeyan ko ba file kọ iwe yi lasiko, ẹjọ naa ko le tẹsiwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja

Loju opo Twitter agbẹnusọ fun Gomina Sanwo Olu ni wọn ti fi tayọtayọ kede aṣeyọri Sanwo Olu pẹlu igbesẹ igbimọ yi

Agbẹjọro fun ẹgbẹ AD ati LP, agbẹjọro Bola Aidi loun dupe lọwọ igbimọ naa fun idajọ ti wọn gbe kalẹ.

Awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ AD, Oloye Owolabi Salis ati akẹgbẹ rẹ lati inu ẹgbẹ LP, Ọjọgbọn Ifagbemi Awamaridi ti saaju kọwe ẹjọ tako iyansipo Sanwoolu pe ko koju oṣunwọn lati dije ipo Gomina.

Bakan naa ni wọn sọ pe ibo Gomina ipinlẹ Eko to waye lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta ni aisedeede ati magomago kun inu rẹ.

O ni Sanwo Olu funra rẹ ko ni kaadi idibo eyi to jẹ ko kuna lati dibo tabi ki wọn dibo fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!