Egypt President: Aàrẹ Morsi torílè-èdè Egypt dákú,ó gba ibẹ̀ derò alákeji

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iku mu Aarẹ Egypt tẹlẹ lọ

Ta ni Mohammed Morsi to ku nile ẹjọ Egypt?

Odun 1951 ni wọn bi Mohammed Morsi ni abule El-Adwah ni ẹkun Nile Delta ti Sharqiya.

O ka ẹkọ nipa iṣẹ imọ ẹ̀rọ ni fasiti Cairo ko to lọ gba oye ọmọwe (Ph.D) ni fasiti kan ni Amẹrika.

Awọn ẹgbẹ Muslim Brotherhood ni wọn fa Morsi kalẹ gẹgẹ bii oludije fun ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2012 ni Egypt.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Diẹ ni odiwọn nọmba to fi bori alatako rẹ ninu idibo to gbe Morsi wọle.

Awọn eniyan Egypt ni ko mu awọn ileri rẹ ṣe lọdun kan to fi ṣe ijọba ki awọn ologun to gba ijọba lọwọ rẹ.

Opolopo iwode lo waye titi ti o fi fipo aarẹ naa silẹ fun awọn ologun.

Gẹgẹ bi ohun ti ile iṣẹ amohunmaworan orile-ede naa sọ aarẹ naa ti awọn ologun yẹ aga nidi rẹ ku nile ẹjọ loni.

Bawo ni Mohammed Morsi ṣe doloogbe?

Aarẹ tẹlẹ ri lorile-ede Egypt, Mohammed Morsi, ti awọn ologun yọ loye lọdun 2013 ti fo sanlẹ ku ninu ile ẹjọ.

Ile iṣẹ amohunmaworan orilẹ-ede Egypt ni o kọkọ daku nile ẹjọ ni ki ọlọjọ to de.

Iroyin naa ni ibi ti aarẹ naa ti n dahun ibeere lo ti kọkọ daku gbọnrangandan ki o to di pe o gba ibẹ re ọrun alakeji.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin nii ṣe.

Ẹsun ìgbéjọ lori gbigba ifitonileti nipa awọn kan labẹlẹ laigba ọna to tọ ni olori ẹsun ti wọn fi kan aarẹ ana naa.

Iwọde nla to ṣẹlẹ lọdun kan lẹyin to gori aleefa lo ṣokunfa bi wọn ṣe yọo nipo.

Oun ni aarẹ akọkọ ti wọn dibo yan lorilẹ-ede Egypt.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Ta ni Morsi?

Aarẹ Morsi Mohammed wa ni atimọle lati igba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ .

Ile iṣẹ amohunmaworan Nile News ni wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ sile iwosan fun iwadii to yẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHuda Shaarawi: Kò dára kí obìnrin sè’yàwó lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá

Ọjọ kẹta, oṣu keje, ọdun 2013 ni awọn ologun gba ijọba lọwọ Mohammed Morsi ni Egypt.

Awọn kan gba pe iwọde to ṣẹlẹ lasiko ijọba Morsi yi lo buru ju lẹyin ti Hosni Mubarak to ṣẹlẹ lọdun 2011.