'Èmi ni afunfèrè àkọ́kọ́ lágbo eré KWAM 1 ní 1983'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kakaki 1: Àwọn òbí mi rí iṣẹ́ orin bí iṣẹ́ alágbe

Peter Olatunde Adeshile ti inagijẹ rẹ lori itage orin jẹ Kakaki 1 afunfere to n da awọn ọmọ Naijiria lara ya loke okun.

Nigba to ṣi wa labẹ obi, ko le fi gbogbo ara tẹle ifẹ rẹ lati maa tẹle awọn elere ni gbogbo igba tori iwe ni awọn rẹ fẹ ko ka.

Orin oni ẹ̀dà Afro ti wọn lu iya ilu si jẹ ọkan lara orin ti Kakaki gbe jade eyi to n ṣafihan aṣa ibilẹ Afirika.

Kakaki jẹ ololufẹ awọn nkan elo orin ilẹ Afirika eyi lo si mu ko maa lo wọn ninu gbogbo awo orin to ba gbe sita bo tilẹ jẹ wi pe oke okun lo ngbe, awọn ọmọ Naijiria to wa nibẹ naa tẹwọ gba aṣa ilu wọn ninu iṣẹ to n ṣe.

Related Topics