Ìtàn Mánigbàgbé: Oyenusi ní òun kò bá tí di adigunjalè, táwọn òbí òun bá lágbára láti rán òun níléèwé

Wọn so Oyenusi ati ikọ adigunjale rẹ mọ agba Image copyright AFP

Yoruba ni ẹni ba jale lo ba ọmọ jẹ, ati pe, bi ole ba da aran bori, asọ ole lo da bora, bi ẹni to ba si jale ba ni ọla laye, ko lee ri ọrun wọ bi ọlọjọ ba de.

Ti eeyan ba gbọ itan igbe aye Isọla Oyenusi, yoo gba lootọ pe bi eeyan ba ni aya, ko sika, ams to ba ri iku Gaa, yoo sọ ootọ nitori bo se gbajumọ bii isana ẹlẹẹta to lasiko aye rẹ fun iwa idigunjale, sibẹ iku ẹsin ati itiju lo ku.

Gẹgẹ ba se ka lori opo Wikipedia lori itakun agbaye, o ni idi ti Oyenusi se gbe igba idigunjale bii isẹ, lẹyin ti ogun abẹle si pari tan lorilẹede Naijiria lo bẹrẹ si fooro awọn ọmọ Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn bi Oyenusi se daamu awọn olugbe ipinlẹ Eko to yii, ina papa dilẹ lẹyin asunsunjẹ rẹ naa ni.

Ta ni Isọla Oyenusi?

 • Ọdun 1970 ni okiki Iṣọla Oyenusi kan gẹgẹ bii adigunjale, to si n da igboro ru lẹyin ogun abẹle to pari, to si n pa eeyan kukuru ati gungun lọsan ati loru, ti kii si jẹ ki awọn eeyan to ba ja lole gbe ile aye di ọjọ keji
 • Oyenusi ati awọn ikọ adigunjale rẹ to jẹ ẹlẹni mẹfa, ni orukọ wọn n jẹ Joseph Osamedike, Ambrose Nwokobia, Joel Amamieye, Philip Ogbolumain, Ademola Adegbitan ati Stephen Ndubuokwu. Gbogbo wọn si lo jingiri ninu iwa gbigba ọkọ ayọkẹlẹ loju ibọn, jija ile ifowopamọ lole, to fi mọ awọn ileesẹ nlanla ati ibudo itaja, bẹẹ si ni wọn n da ẹmi awọn alaisẹ ọmọ Naijiria legbodo lojoojumọ
 • Oyenusi, lo sọ ara rẹ di Dokita ọsan gangan, tawọn eeyan si mọ si Dokita ajanilole pani, to si di Dokita ọsan gangan lai lọ sile iwe girama lasan debi ileẹkọ fasiti
 • Oyenusi la gbọ pe o ni ifẹ pupọ, paapa si abo, to si jẹ pe o gunle iwa idigunjale rẹ nitori pe ọrẹbinrin rẹ nilo irinwo Naira pere, eyi ti agbara Oyenusi ko ka, to si tori eyi bẹrẹ si ni gbe ibọn
 • Oyenusi lọ ja ọkọ kan gba, to si ta mọto naa ni irinwo naira, eyi tii se deede iye owo ti ọrẹbinrin rẹ nilo, to si ko fun.
 • Dokita adigunjale ta n sọrọ rẹ yii jẹ oninu fufu ẹda, to si gberaga pupọ, koda se lo pariwo mọ ọlọpa to wa mu pe oun ko fẹ bo se n ba oun sọrọ, nitori to ba jẹ pe oun gbe ibọn dani ni, oun ko ba ti fi ibọn pa
 • Lasiko ti ina idigunjale n jo fun Oyenusi, Oyenusi maa n janu pe ibọn ko ni agbara lori oun, tawọn eeyan si ri ogbologbo adigunjale naa bii Adigunjale akọkọ to gba ipo kinni yika orilẹede Naijiria.Lẹyin rẹ si lawọn adigunjale yoku to ti fi Naijiria logbologbo to si
 • Sugbọn ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kansoso pere ni ti olohun. Ọwọ palaba Oyenusi ati awọn ẹmẹwa rẹ ninu iwa idigunjale papa segi lọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹta ọdun 1971 nigba to yinbọn pa ọlọpa kan, ọgbẹni Nwi, lasiko ti wọn lọ digun jale, to si ji ẹgbẹrun lọna mejidinlọgbọn pọnun nigba naa
 • Kia lawọn ọlọpa wa Oyenusi ni awari, ti wọn si gbe lọ sile ẹjọ lati wa jẹwọ awọn iwa ẹsẹ to ti gbe ile aye hu. Ileejọ sọ pe o jẹbi ẹsun idigunjale, ipaniyan, idaluru ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti adajọ si ni ki wọn lọ fi ẹyin rẹ ti agba, ki wọn rọ ibọn fun oun ati awọn ikọ adigunjale rẹ, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ
 • Ọjọ ni ọjọ ti wọn fi ẹmi Oyenusi ti agba, pẹpẹyẹ pọnmọ. Ara oko wale, ti ẹniti ko lee rin si ni ki wọn gbe oun nitori o le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn oluworan to wa wo oju ole Oyenusi ati bo se fẹ ku iku oro, bẹẹ si lawọn onworan naa n fi se ẹlẹya
 • Ko to di pe Oyenusi gba ọta ibọn sara, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ikẹyin, Oyenusi ni abamọ lo gbẹyin ọrọ fun oun ninu isẹ ibi ti oun rawọ le. O si fi ika hanu pe to ba jẹ pe awọn obi oun lagbara lati ran oun lọ sile iwe ni, oun ko ba ti dawọle isẹ adigunjale to wa gba ẹmi oun naa
 • O ni iya ẹsẹ ti oun sẹ ni oun fẹ ku le lori yii, ọrọ Ọlọrun si lo sẹ mọ oun lara pe, ẹni to ba fi ida pa eniyan, lati ipa ida naa ni yoo fi ku, amọ ki Ọlọrun fori jin oun .
 • Se ni Oyenusi n laagun lakọlakọ lasiko ti wọn fi ọkọ ẹlẹwọn black Maria ko oun ati awọn ẹmẹwa rẹ de, amọ o n rẹrin, rẹrin titi ti wọn fi fi okun so mọ agba, amọ o nira fun lati fi ẹrin musẹ bo ibẹrubojo ati abamọ to loju rẹ, tawọn ologun si yinbọn fun lẹyin o rẹyin.

Dokita Iṣọla Oyenusi waye amọ ko se aye re. Ori awọn obi rẹ si lo di ẹbi igbe aye to buru, to gbe naa le, eyi to yẹ ko jẹ ẹkọ fun awa obi pe, o yẹ ka kọ ọmọ wa, ko lee fun wa ni isinmi.

Obi ti ko ba lagbara lati kọ ọmọ rẹ ni ẹkọ iwe, yẹ ko fi si ẹnu ẹkọsẹ abi okoowo nitori ọwọ to ba dilẹ ni esu n bẹ lọwẹ.

Image copyright AFP

Bakan naa si lawọn ọdọlangba gbọdọ kọgbọn pe, ifẹ abo tabi akọ ko gbọdọ ti awọn ni itikuti lati siwa hu.

Related Topics