Oyo Algon: Agbẹjọ́rò ìjọba Ọyọ ní Makinde kò tí ì rí ìwé ìpẹ̀jọ́

Seyi Makinde Image copyright Seyi@official
Àkọlé àwòrán Local Government Dissolusion: Ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù keje ní igbéjọ yóò wáye ló ìjọba ibílẹ̀ Ọyọ.

Ilé ẹjọ tó ga jùlọ ní Ibadan ní ohun yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ lóri ẹjọ tí àwọn ẹgbẹ́ alága ìjọba ìbílẹ̀ nipinlẹ Ọyọ, (ALGON) gbé wá lóri àṣẹ tí gómìnà Seyi Makinde pa pé ki gbogbo alága ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀yọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ló maa simi nilé.

Ẹgbẹ́ ALGON, tí Ọgbẹ́ni Kunle Sobaloju jẹ́ agbẹjọ́rò wọn, dárukọ agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ asofin , kọmisọna fọrọ ijọba ibilẹ̀, kọmisọna fun ètò ìdájọ àtí agbẹjọrò àgbà ìpínlẹ̀ Oyo nínú ìwé ẹsùn náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sobaloju ni, sááju ni ilé ẹjọ ti pàṣẹ fun Makinde lati máṣe tú àwọn alága ijọba ìbílẹ̀ náà ka, sùgban gómìnà kọti ọgbọnin si aṣẹ náà, ní kéte ti wọ́n bura fún-un wọle tan.

Sobaloju sàlàyé fún ile ẹjọ́ pe, iwé ìpẹ̀jọ láti da gomina duro lóri aṣẹ̀ náà ní wọ́n gbé wá silé ẹjọ ni ọjọ kẹwàá oṣù kẹfa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ni afunfèrè àkọ́kọ́ lágbo eré KWAM 1 ní 1983'

O sàlàyé pe, gómìnà ń gbé ìgbéṣẹ̀ láti yan àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ alámojuto fún àwọn ìjọba ibilẹ.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọrò fún ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, Ọgbẹ́ni Oluwaseun Dada sọ fún ilé ẹjọ́ pe, iwé ìpẹ̀jọ pe ki Makinde ma tú ilé ka kò ti dé ọdọ àwọ̀n, nítori náà ko tíi yẹ fún ìgbẹ́jọ.