Erin fara gbọgbẹ̀, ó ṣekú pa ènìyàn méjì ni Liberia

Erin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Erin

Erin kan to fara gbọgbẹ ti doju ija kọ awọn eeyan agbegbe ila oorun ariwa Liberia ti o si ṣeku pa eeyan meji.

Lara awọn to fara kasa ibinu erin naa ni baba ẹni ọdun mejidinlọgọta kan ati ọmọ rẹ ọkunrin.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn to n pa ẹran lọna aitọ lo yinbọn lu erin naa ninu igbo Gbarpolu.

Nibi ti o ti n sa asala fun ẹmi rẹ lo ti pade baba naa ti o si ṣeku pa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Ọmọ baba ọhun ti o n tọ baba rẹ lọ naa pade agbako iku lọdọ erin naa.

Iṣẹlẹ pipa awọn erin lọna aitọ kii ṣe tuntun lawọn orileede kan ni Afrika.

Lọpọ igba awọn to n pa awọn ẹranko wọnyii a ma ta ẹya ara wọn lowo iyebiye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadoja