Ìjọba Ọṣun: Ẹ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa láti gbé Ọṣun Oṣogbo dé ibi gíga ní 2019

Ọdun Ọsun Osogbo Image copyright @osunosogbo2019

Ijọba ipinlẹ Ọsun ti fọwọ idaniloju sọya pe, didun ni ọsan yoo so lasiko ọdun Ọsun Osogbo ti yoo waye lọdun 2019 ta wa yii, ti ohun gbogbo yoo si lọ ni irọwọrọsẹ, eyi ti yoo jẹ iwuri fun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.

Alakoso feto abẹle, asa ati irinajo afẹ nipinlẹ Ọsun, Ọmọwe Ọbawale Adebisi lo fọwọ idaniloju yii sọya lorukọ ijọba ipinlẹ naa, lasiko to lọ se abẹwo si ileesẹ kan to n soju fun ileesẹ eto irinajo afẹ ni Naijiria ati ibudo ise nkan isẹmbaye lọjọ si, eyi ti Ọgbẹni Toye Arulogun n dari rẹ.

Ọmọwe Adebisi ni ohun amuyangan ni Ọsun Osogbo jẹ, o si yẹ ka wa ọna lati jẹ ki ọwọ okiki ati anfaani okoowo to n mu wa maa tẹsiwaju fun ipinlẹ Ọsun ni, gẹgẹ bii ipinlẹ to n dokoowo ninu asa ibilẹ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adebisi ni " A maa tẹsiwaju lati wa ajọsepọ pẹlu ẹlẹgbẹjẹgbẹ, ẹnikẹni tabi ileesẹ kileesẹ to ba setan lati mu agbega ba eto irinajo afẹ ni ipinlẹ Ọsun, a si n fi oju sọna fun ajọsepọ to loorin pẹlu ẹka aladani."

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Toye Arulogun jẹjẹ atilẹyin ileesẹ naa lati ri daju pe asa ọdun Ọsun Osogbo ko yinjẹ, ti awọn yoo si tun fi akọtun ọgbọn si ọna ti wọn n gba se ọdun naa.

Image copyright @osunosogbo2019

O ni eyi yoo tubọ fa oju awọn eeyan mọra si jakejado agbaye, eyi ti yoo mu ki ọdun asa ibilẹ, irin ajo afẹ ati ogun abalaye wa naa se aseye, ti alakan n se epo lọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ni afunfèrè àkọ́kọ́ lágbo eré KWAM 1 ní 1983'

Arulogun fikun pe "a fẹ ki ọdun Ọsun Osogbo si tẹsiwaju lati maa jẹ ọdun fun eto irinajo afẹ lagbaye pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ Ọsun. Atilẹyin ijọba ipinlẹ Ọsun si se pataki fun aseyọri ọdun Ọsun Osogbo lọdun 2019 yii, baa se n dijọ se agbelarugẹ, itaniji, idaabobo ati ifẹsẹmulẹ ọdun Ọsun Osogbo to se ara ọtọ naa."