Kidnapping: Kò sẹ́ni tó mọ̀ bóyá àwọn ajínigbé gba owó ìtúsílẹ̀

Isaac Adewole Image copyright @IsaacFAdewole

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni ọmọ minisita tẹlẹri fun eto ilera, Dayọ Adewọle ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Iwe iroyin Punch lo gbe e jade wi pe, ọkunrin naa gba itusilẹ lai pe wakati mẹrinlelogun ti wọn jigbe lọ.

Amọ, iroyin naa fikun wi pe, awọn ko mọ boya wọn san owo itusilẹ.

Owurọ Ọjọru ni iroyin gbe e jade pé lójúnà oko ni wọ́n ti jí Deji Adewole gbe ní ìlú Fiditi, ipinlẹ Oyo.

Oyo Police:: A ti rí ọkọ̀ méjì tí àwọn ajínigbé lò láti jí Dayọ Adewọle

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti mu afurasi mẹta to jẹ osisẹ ni oko ti wọn ti ji Dayo Adewole, to jẹ ọmọ minisita fun eto ilera tẹlẹri Isaac Adewole naa gbe.

Alukoro ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi lo fi ọrọ yii lede, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ibi ti wọn ba isẹ de lori iwadii itọpinpin lori ijinigbe ọmọ minisita naa.

Fadeyi ni kete ti isẹlẹ naa waye, ni wọn ti bẹrẹ iwadii, ti wọn si ti ri ọkọ mejeeji ti wọn fi ji ọmọ minisita naa gbe ninu igbo, ti wọn si ti gba a pada.

O fikun wi pe, awọn ajinigbe naa ko i ti i kan si ẹbi ati ara ẹni ti wọn jigbe. Bakan naa ni wọn ko i tii beere owo itusilẹ ni ọwọ awọn ẹbi.

Alukoro ile isẹ ọlọpaa naa wa rọ awọn ara ilu, lati ran awọn lọwọ lati fi iroyin lede ti wọn ba gbọ nkankan, nitori awọn ọlọpaa gbagbọ wi pe awọn ajinigbe yii n gbe laaarin awọn eniyan ninu ilu.

Ọmọ Mínísítà àná, Adewole bọ́ s'ọ́wọ́ ajínigbé

Ọmọ ọkunrin minisita tẹlẹ ri fun eto ilera Isaac Adewole, iyẹn Dayo Adewole ti bọ sọwọ̀ awọn ajinigbe.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe lojuna oko ni wọn ti ji i gbe nilu Iroko nitosi Fiditi, ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná Ibadan: Gbogbo dúkìá tó wà lókè ilé alájà kan náà ló jóná tán

Iṣẹlẹ ijinigbe laipẹ yii lorilẹede Naijiria paapaa iha Guusu Iwọ-Oorun ti di ohun to n kọ ọpọlọpọ lomiinu ti ko si yọ olowo tabi talaka silẹ.

Dayo Adewole to jẹ ọmọ minisita tẹlẹ ri fun eto ilera ni àwọ̀n àwọn ajinigbe tun gbe lọtẹ yii.

Iroyin sọ pe ṣe lawọn agbebọn da a lọna oko ti wọn si ji i gbe lọ ibi aimọ. Eyi tilẹ ti mu ki minisita ana, Ọjọgbọn Isaac Adewole ge irinajo rẹ lo soke okun kuru lojiji.

Lọwọ lọwọ, awọn ọlọpaa, oṣiṣẹ alaabo atawọn ọlọdẹ ibilẹ ti kan lu agbami iṣẹ wiwa Dayo.

Awọn ajinigbe kọ, wọn ko tii kan si idile ọmọ naa lori ohun to ṣokunfa eyi ati ipo ti ọmọ naa wa bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo bí o ṣe lè kọ ẹ̀nu ìfẹ́ sí obìnrin pẹ̀lú ohun èlò orin yìí

Awọn oṣiṣẹ baba rẹ to n kọwọ rin pẹlu rẹ ti ori yọ lo figbe ta si awọn araalu ti Oniroko ti ilu Iroko si tete ko awọn ọlọdẹ jọ.

Ṣugbọn di bi a ṣe n sọrọ yii, wọn ko tii mọ ipo tabi ibi ti Dayo Adewole to fi mọ awọn to ji i gbe wa.