Gani Adams: OPC ti ṣe tán láti kojú ìpèníjà ààbò ilẹ̀ Yorùbá

Gani Adams Image copyright Gani Adams/facebook

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, to tun jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara Oodua Peoples Congress, OPC sọ pe ẹgbẹ naa ti ṣe tan lati ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati gbogun ti ijinigbe ati awọn ipenija mii to n koju eto aabo nilẹ Yoruba.

Aarẹ Adams sọ ọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba ni ifesi si ipade to laarin rẹ ati aṣoju ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria nilu Eko lọjọ Iṣẹgun.

O ni ijomitoro lori ọ̀rọ̀ eto aabo ilẹ Yoruba ni ipade naa da le lori ṣugbọn ko fi bẹẹ kii ṣe ohun teeyan kan le maa sọ lori ẹrọ ibara ẹni sọrọ.

Ṣaaju ninu ifọrọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba lori eto aabo, Gani Adams sọ fun wa pe ẹgbẹ OPC ko le da si ọrọ aabo Naijiria ti ijọba ko ba pe e si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Ṣugbọn nibayii ti ọga ileeṣẹ ọlọpaa ti kan si olori ẹgbẹ naa, kini yoo jẹ ṣiṣe?

Lori eyi, Adams sọ fun wa pe "Ọlọpaa to ba mọ pe oun fẹ ṣe aṣeyọri kun aseyọri gbọdọ ba ẹgbẹ OPC ṣe papọ.

Ọga ọlọpaa patapata ran ẹni naa lati ṣe ipade pẹlu OPC pe oun nilo iranlọwọ ẹgbẹ naa.

Ajọ fẹnuko nibi ipade naa pe ao jọ ṣiṣẹ pọ, ṣugbọn gbogbo nkan lo ni eto. Gẹgẹ bi a ti ṣe pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lori ọrọ Badoo to n paayan.

Ati ṣe tan lati ran wọn lọwọ, ọwọ wọn lo ku si." O ni tori ọrọ ijọba kii ya nigba miiran bi o tilẹ jẹ pe awọn jọ ṣepade.

Ṣaaju ni ẹgbẹ kan t'oun naa n jijagbara nilẹ Yoruba, Ẹgbẹ Agbẹkọya sọ fun BBC pe 'oogun abẹnugọngọ ni na abayọ si ọrọ awọn ajinigbe.' Ati pe awọn ti ṣe tan lati koju wọn ti ijọba ba le fun wọn ni aaye lati ṣe bẹẹ.

Agbekoya: Bí a bá na oògùn abẹnugọ̀ngọ̀ s'ókè, ìjínigbé á d'ópin!

Ọmọ Mínísítà àná, Adewole bọ́ s'ọ́wọ́ ajínigbé

Lori boya o ṣeeṣe ki ẹgbẹ OPC ati ẹgbẹ ajijagbara Agbẹkọya jọ ṣiṣẹ pọ lori eto aabo, Aarẹ Adams sọ pe ẹgbẹ agbẹkọya naa ni iwulo fun ilẹ Yoruba lori eto aabo.

"Ọrọ to wa nilẹ yii kii ṣe ti OPC nikan, a fẹ ri i daju pe gbogbo awọn ẹgbẹ to ni nkan ṣe pẹlu eto aabo lati jẹ ki wọn o wulo. Pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọba ati alaga ijọba ibilẹ awọn gomina.

Gani Adams ni ipade apero kan n bọ laipẹ 'Yoruba Summit', ti gbogbo ẹgbẹ to ni nkan ṣe pẹlu aato aabo yoo ti jiroro lori eto aabo.

Pẹlu ipade ti a ṣe pẹlu awọn ọlọpaa yii, ao kọkọ maa dọgbọn ba wọn ṣiṣẹ papọ ki ọrọ awọn ajinigbe yii to wọ wa lara tan, nitori pe ọrọ ijọba kii ya bọrọ."