Osinbajo: Ọmọ Nàìjíríà, nǹkan kò ní pé ṣẹnure fún mẹ̀kúnù

Yemi Osinbajo Image copyright yemi osinbajo
Àkọlé àwòrán Ìgbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo rọ ọmọ Nàìjíríà pé ǹkan ò ni pé ṣẹnure fún mẹ̀kúnù

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo ní òsí àti ìṣẹ́ tó ba orilẹ̀-èdè Nàìjíríà jà kìí jẹ ki òun ri òòrun sùn lóru.

Osinbajo sọ èyí di mímọ̀ níbi àpérò kan ní ìpínlẹ̀ Eko, O ní " mó ro pé ǹkan tí kìí jẹ́ ki n sùn lórun ni bí òsì àti ìṣk ṣe gbilẹ̀ tó ni orílẹ̀-èdè yiìí àti pé ọ̀pọ̀ àwọn yo dìbò fún wa ní àwọ otoṣì pátápátá yìí."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná Ibadan: Gbogbo dúkìá tó wà lókè ilé alájà kan náà ló jóná tán

"Ìléri ti ìjọba ṣe fún wọ́n ni pe ayé wọn yóò ni ojúùtú, sùgbọ́n ìréti wọn ni pe kò ni pẹ́ rárá"

"Inú mi kìí ba dùn ti mo ba rí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi èyí tii yóò ma ṣe ìdásilẹ̀ oníruuru ilé iṣẹ́ ni ọdun mẹ́wàá sasiko yii, tí ọ̀pọ̀ eeyan yóò si kúrò ninu iṣẹ́ to n bá wọ́n fíra."

Osinbajò ní, ọ̀pọ̀ àwọn ìlàna àmúlò ìjọba ní ó dúrò lóri fifi àwọn òtòsì sọ́kàn, pẹ̀lú àfọkan si lóri ètò ọ̀gbìn àti láti máà gbe owoya fún àwọn àgbẹ, ki wọn lee ni aníto àti ànisẹkun.