Ìtàn Mánigbàgbé: Ayinla Ọmọwura kò kàwé, àmọ́ ó kópa sí àgbéga orin àti èdè Yorùbá

Image copyright Ayinla Omowura

Ni ilẹ Yoruba, awọn ẹja nla ti lọ lomi, awọn ajanaku ti sun bi oke, awọn erin ti wo niju, ti wọn ko si lee dide.

Ta ba si ni ka maa ka awọn erin nla to ti wo naa ni eni, eji, ẹta, ilẹ ti wẹ, nitori ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ si ti fi mu, ni oniruuru ẹka igbe aye ọmọniyan paapa ni ẹka awọn amuludun.

Ọkan lara awọn manigbagbe amuludun nilẹ Yoruba, ti onirese wọn ko fin igba mọ, amọ to jẹ pe eyi ti wọn ti fin silẹ ko lee parun ni Waidi Ayinla Ọmọwura, ti gbogbo eeyan mọ si Eegunmọgaji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko yẹ ki iran ode oni ma mọ itan igbe aye Ayinla Ọmọwura rara, nitori odu ni fun oloko lawujọ awọn olorin.

Bẹẹ, iyọ rẹ ko tẹ lawujọ awọn erupẹ nigba aye rẹ, idi si ree ti a se gbe itan aye rẹ wa fun un yin gẹgẹ bi a se ka a lori itakun agbaye Wikipedia ati awọn oju opo ayelujara miran.

Image copyright Ayinla Omowura
Àkọlé àwòrán Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin

Taa ni Ayinla Ọmọwura?

 • Waidi Ayinla Ọmọwura fori sọlẹ si adugbo Itoko, ni ilu Abẹokuta lọdun 1933, bi o tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ọjọ ti wọn bii, nitori ko si akọsilẹ nipa ọjọ ibi rẹ lasiko to de ile aye.
 • Orukọ baba rẹ ni Yusuff Gbogbolowo, tii se alagbẹdẹ ati orukọ iya rẹ ni Wuramọtu Morẹnikẹ, gẹgẹ bo se maa n ki ara rẹ.
 • Isẹ alagbẹdẹ ti baba rẹ n se ni Ayinla Ọmọwura kọkọ kọ bii isẹ oojọ nigba aye rẹ, nigba to ya lo tun kọ isẹ ọkọ wiwa, to si se isẹ awakọ fun igba kan.
 • Ko pẹ lo tun bẹrẹ orin apala kikọ, to si wa ni sawawu awọn ilumọọka akọrin bii Haruna Iṣọla, Ligali Mukaiba, Fatai Ayilara, Ojubanirẹ Tẹwọgbade, Kasumu Adio ati Yusuff Ọlatunji.
 • Isẹ orin kikọ gbe Ayinla Ọmọwura pupọ, ka si to sẹju pẹ, o ti se awo orin to to mejilelogun ko to papo da, ti okiki rẹ si gba gbogbo ilẹ Yoruba kan nigba aye rẹ, boya nitori ede Ẹgba to fi n kọ orin Apala tiẹ ni, ko sẹni to ye
 • Ayinla Ọmọwura jẹ akọrin makọtisẹ ninu awọn awo orin to gbe jade naa, orin rẹ si ti yi igbe-aye ọpọ eeyan pada si rere, paapa awọn obinrin ojowu, obinrin to n bóra ati awọn onipanle obinrin, tii se ori bẹnbẹ si ọkọ.
 • Ninu awo orin rẹ kẹẹdogun (Vol 15) to pe ni "Ọrọ kan jẹ mi logun", lo ti ba wọn wi. O ṣapejuwe awọn obinrin to n bora bii alawọ ọpọlọ. Inu awo orin "Pansaga ranti ọjọ ọla", si lo ti tahun si awọn obinrin oninabi.
 • Orin Ayinla Ọmọwura tun maa n kun fun ijinlẹ ọrọ Yoruba, owe, akanlo ede ati imọran.
 • Eyi lo jẹ ki ọpọ ọmọ Kaarọ Oojire yan orin rẹ ni aayo, paapaa awọn obinrin to n ta ọti bia ni ilu Abẹokuta ati Mushin.
 • Koda, o tiẹ fi awo orin kan ki awọn obinrin to si sọọbu ọti tita, eyi ti awujọ tako. Lede kan, agbọ-mujojo ni orin Ayinla Ọmọwura nigba aye rẹ
 • Yatọ si pe orin Ayinla Ọmọwura n mu iyipada rere ba awujọ, orin rẹ tun kun fun ọfọ, ayajọ ati epe nigba miran eyi to mu ki ọpọ eeyan maa ri i bi oloogun.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Iru iku wo lo pa Ayinla Ọmọwura?

 • Itan ati ẹkọ nla miran lo rọ mọ bi Ayinla Ọmọwura se lọ si ọrun ọsan gangan lọjọ aipe ati ni ọna to jẹ iyalẹnu.
 • A gbọ pe Alakoso agbo orin Ayinla Ọmọwura, Bayewu ni oun ati Ayinla jọ ni ikunsinu, ti Bayewu si fi ọdọ Ayinla silẹ lai gbe ọkada to fun un lati fi sisẹ silẹ nigba to n lọ.
 • Ile ọti ni Bayewu ati Ayinla ti fi oju rinju, ti ija si sọ laarin wọn.
 • Ninu ija yii ni wọn ti sọ ọrọ kobakungbe sira wọn, ti inu si bi Bayewu debi pe o gbe gilaasi to fi n mu bia, to si la a mọ Ayinla Ọmọwura lori.
 • Alaye yii ko fidi mulẹ to, nitori ọpọ eeyan lo n beere pe ṣe ife ọti lasan to lati gbẹmi eeyan, amọ awọn eeyan kan woye pe o ṣeeṣe ki Ayinla Ọmọwura ti ṣe oogun abẹnu gọngọ debi pe ko gbọdọ kan ẹjẹ.
 • Niwọn igba to ṣe pe ẹni to ba pa eeyan, pipa naa ni wọn yoo pa, wọn wọ Bayewu lọ sile ẹjọ, ti adajọ si da ẹjọ iku fun oun naa lẹyin ọdun diẹ, ti wọn si yẹ igi fun-un.
 • Amọ, o ṣeni laanu pe ẹni ọdun mẹtadinlaadọta pere ni Ayinla Ọmọwura ni ọjọ Kẹfa, osu Karun un, ọdun 1980 to dagbere faye pe o digbose.
 • Kokoro ko si jẹ ka gbadun obi Ayinla to gbo, ti iku ko jẹ ka gbadun ohun aladun ti Ẹlẹda fi jinki Ayinla Ọmọwura.
Image copyright Ayinla Omowura
Àkọlé àwòrán Kokoro ko si jẹ ka gbadun obi Ayinla to gbo, ti iku ko jẹ ka gbadun ohun aladun ti Ẹlẹda fi jinki Ayinla Ọmọwura.

Ayinla Ọmọwura ko lọ sile iwe rara, amọ o se iwọn to lee se lati ko ipa tiẹ si idagbasoke awujọ to wa lati ipasẹ orin kikọ ati gbolohun ede Yoruba.

Ọba oke fi ohun to gbooro, to si dun un gbọ leti jinki Ayinla Ọmọwura pẹlu awọn agberin ti ọpọlọ wọn ji pepe kẹẹ.

Eyi to mu ki orin kikọ rọ Ayinla Ọmọwura lọrun. Lootọ ni Ayinla Ọmọwura jẹ ọmọ atapata dide amọ, o koju ọpọ ipenija to ba nile aye, to si bori wọn.

Ọpọ eeyan si lo gba pe akikanju akọrin ni Ayinla Ọmọwura, bẹẹ si ni ọjọ ko lọ lori awọn awo orin to ṣe lati ọpọ ọdun sẹyin, to si fi aikawe rẹ jẹ amuludun fun iran Yoruba.

A si n gbadura pe Ọlọrun yoo fi ọrun kẹ ẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Related Topics