Aisha Buhari: Ìjọba kò le è ṣe àmúṣẹ ìlérí rẹ̀ tó bá yan alátakò sípò

Aisha Buhari Image copyright @aishmbuhari

Yoruba ni bi ara ile ẹni ba n jẹ kokoro buruku, ti a ko ba tete sọ fun, hẹrẹ-huru rẹ ko ni jẹ ka sun lori.

Boya eyi lo mu ki aya aarẹ Naijiria, Aisha Buhari fi n ke tantan loju opo Twitter rẹ pe, ko dara ki awọn eeyan ti ko ba awọn ọmọ ẹgbẹ APC jiya ka to dibo, maa wa jẹ igbadun ijọba lẹyin eto idibo.

Imọran yii ni aya aarẹ fi n se atilẹyin fun awọn ọdọ kan ninu ẹgbẹ oselu APC, ti wọn n fi apa janu pe awọn alatako ti ko gbagbọ ninu awọn afojusun ijọba Muhammadu Buhari, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC n yan sipo .

Awọn ọdọ naa, ninu fọnran aworan ti wọn fi sita, eyi to n ja rainrain lori ayelujara, tun salaye pe kii se iyansipo ti aarẹ ile asofin agba se laipẹ yii nikan ni awọn n mẹnuba, amọ awọn n sọ nipa gbogbo eto iyansipo to n waye gan ni labẹ ijọba apapọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ni "ẹni to ba se ni idi pẹpẹ, lo yẹ ko jẹ ni idi pẹpẹ, bi ijọba ko ba si gbe igbesẹ to tọ ni idi iyansipo rẹ, ko fi ika to ba tọ si imu, re imu, awọn yoo fi ọwọ ara awọn tun iwa ara awọn se, eyi to lee lẹyin ti ko dara fun ijọba to wa lode bayii.

Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba mu iroyin kan wa fun yin laipẹ yii pe, aarẹ ile asofin agba, Ahmed Lawan yan Ọmọwe Festus Adedayọ ni amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, amọ tawọn eeyan kan n fapa janu nipa iyansipo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Wọn ni alatako ijọba Buhari ni Adedayọ, idi si ree ti ko fi tọ lati gba ipo ọhun.

Lẹyin o rẹyin ni wọn kede pe wọn ti yọ orukọ Festus Adedayọ kuro, ti wọn si yan ẹlomiran rọpo rẹ.