#FIFAWWC : Chile fi àmì àyo méjì gbógo fún Naijiria

fans Image copyright @Daniela
Àkọlé àwòrán Super Falcons gòkè odò bọ́ sípele ìkẹrìndínlógún ní France

Cameroun ati Naijiria ti yege fun ipele to kan ni FIFAWWC.

Ami ayo meji ni ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede Chile fi na Thailand ninu idije ifẹ ẹyẹ agbaye tawọn obinrin to n lọ lọwọ ni France.

Image copyright @thenff
Àkọlé àwòrán Cameroun ti yege fun ipele to kan ṣugbọn nnkan ko tii ṣẹnuure fun Naijiria

Ifagagbaga to waye laarin Thailand ati Chile lo sọ boya Naijiria ṣi maa tẹsiwaju ninu idije tabi bẹẹkọ nitoripe France ti na Naijiria ninu ikọ naa pẹlu ami ayo kan tẹlẹ.

Bayii Naijiria ti pegede lati kopa ninu idije oni ikẹrindinlogun ko mẹsẹ o yọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFlorida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Inú fu, àyà fu ni Naijiria wà tẹ́lẹ̀

Ikọ super Falcons, tii se agbabọọlu obinrin fun orilẹ-ede Naijiria atawọn ọmọ Naijiria, yoo kun fun adura lati gba idajọ rere nipa ati tẹ siwaju ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorilẹ-ede France.

Ọjọ iṣẹgun ni orilẹ-ede Naijiria gba ifẹsẹwọnsẹ to gbẹyin ninu ipin wọn fun ipele akọkọ idije ife ẹyẹ agbaye FIFA naa, ṣugbọn ipo kẹta ni Falcons ṣe lẹyin France ati Norway.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ami ayo meji si odo ni wọn fi na South Korea, eyi to fun wọn lanfani ati duro mọ boya wọn yoo wa lara awọn ti ori yoo ko yọ lati kopa ni ipele to kan.

Ṣiugbọn lẹyin ti orilẹ-ede Cameroun ti gbẹyẹ mọ New Zealand lọwọ pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan, ọwọ orilẹ-ede Thailand, tii yoo maa waako pẹlu Chile bayii ni idajọ ku si, lati mọ boya Falcons yoo tẹsiwaju tabi tẹ ọkọ leti pada sorilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Bi orilẹ-ede Thailand ba gba ki Chile gba ayo to ju meji si awọn rẹ, a jẹ wi pe orilẹ-ede Naijiria yoo ja kuro ni ipele to kan.

Sugbọn ṣa, bi Thailand ba lee ṣe bi ọkunrin ti wọn ko gba ki Chile gba ayo ju ẹyọ kan tabi meji si awọn wọn, gba ọmi tabi na Chile, taara ta ni Falcons yoo lọ si ipele to kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele