Florida: Ọọ̀nì àléégbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Florida: Ọọ̀nì àléégbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

To ba jẹ iwọ, kini o maa ṣe?

Ọpọ igba ni eeyan maa n gba awọn alejo to wu ni lati gba pẹlu ayọ ati idunnu.

Ṣugbọn igba mii awọn alejo òjijì kan maa n ba ni lalejo ti eniyan maa maa sa kiri inu ile fun.

Iru eyi ni Mary Wischuhusen gba laarin oru ni iyara idana rẹ ni Florida.

Mary jẹ arugbo ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin to n gbe ni Florida ni orilẹ-ede America.

Lojiji lọganjọ oru lo gbọ ariwo nile idana rẹ to fi ri i pe ọọni aleegba ti wa ba oun lalejo.

Ọpẹlọpẹ ọdẹ to baa mu ọọni to gun kọja mítà mẹta naa.