Nigeria Army: àṣírí àwọn ajínigbé kò bò mọ́ ni Ondo àti Ekiti

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Nigeria Army: àṣírí àwọn ajínigbé kò bò mọ́ ni Ondo àti Ekiti

Kete ti ijọba apapọ ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ ogun lo mojuto ọrọ awọn ajinigbe ni iṣẹ ti bẹrẹ.

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ ijinigbe lo ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria lasiko yii ni eyi to n kọ ọpọ olori lominu.

Koda laipẹ yii ni wọn ṣi ji ọmọ minista eto ilera, Ojogbon Adewole gbe ki awọn agbofinro to rii padaỌmọ isaac Adewọle gba ìdáǹdè lọ́wọ́ ajínigbé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIbadan expressway: Àwọn olè Fulani ló ń jí ènìyàn, pànìyàn ní òpópópónà!

Ileeṣẹ ologun ṣalaye pe awọn ẹrọ ayaworan to n fo lofurufu yii ni awọn yoo lo lati ṣawari ibúba awọn ajinigbe lawọn ipinlẹ yii.

Lọjọ Eti ni wọn ṣe ifilọlẹ awọn ẹrọ yii ni Osi ni Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Ogagun agba Zakari Abubakar to jẹ adari ikọ ọmọ ogun ni ẹkun yii ṣalaye pe awọn ẹrọ yii a maa ṣiṣẹ laarin ipinlẹ mejeeji tọrọ kan ni

Ogagun Zakari ni Ogagaun agba Tukur Buratai ti paṣẹ lati Abuja pe ijinigbe gbọdọ dopin ni ẹkun yi lẹyẹ-o-soka.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti

Ọgagun Buratai to n dari gbogbo ọmọ ogun Naijiria ni lilo awọn irinṣe igbalode bi eyi yoo tete jẹ ki iṣẹ naa rọrun lati ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Owó tí mo ń rí lórí Garri ni mo fi ń ran ọkọ lọ́wọ́'

Ogagun Abubakar ni ikọ omo ogun oriṣi meji ti wọn kọkọ gbe kalẹ lati gbogun ti ijinigbe ni yoo jọ lo ẹro yii lati mu ayipada de ba eto aabo awọn eniyan ipinlẹ Ondo ati Ekiti

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYSAN 2018: llú Ondo gbàlejò Àpérò Ẹgbẹ́ Onímọ̀ èdè Yorùbá Nàìjírìa

Ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ ni aja iwoyi lo mọ ehoro iwoyii lé ni awọn fi ọrọ yii ṣe.

O ni igbo kijikiji to wa ni agbegbe yii ni awọn kan ti sọ di ibuba wọn fun iṣẹ ibi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

Ogagun Azinta to jẹ olori ikọ ọmọ ogun ni ẹkun yii ni wọn ti paṣẹ fun pe ko rii pe gbogbo ọmọ ogun sá ipa wọn fun alaafia awọn eniyan Ekiti ati Ondo ti wọn n gbe ninu ipaya bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Igbe àwọn ọ̀dọ́ kọ́ ló mú wa pèsè iná l'Ondo'

Awọn ọmọ ogun wa fi da gbogbo awọn arinrinajo loju pe ko nii sewu mọ lopopona lati isinyii lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Iya lu ọmọ pa nítori ẹgbẹ̀rún mọkànlélógun Naira

Wọn ni awọn ikọ tijọba ṣagbekalẹ lati gbogun ti awọn ajinigbe ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu ni agbegbe yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Igbagbọ awọn eniyan ipinlẹ Ondo ati Ekiti ni pe laipẹ ni wọn yoo le tun maa fẹdọ sori oronro sun bii ti tẹlẹ pẹlu igbesẹ tuntun ti awọn ọmọ ogun gbe yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo; 1000 si 2000 naira lowo ori ilẹ fun mẹkunu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti pa ìjọba dà lẹ́yìn tí wọ́n kéde Fayẹmi