Olorí ogun Ethiopia f'arapa nínú rògbòdìyàn tó wáyé ni Addis Ababa

Abiy Ahmed Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lootọ ni Ọgbẹni Abiy pa ina wahala oṣelu, amọ ija ẹlẹyamẹya n pọ si

Igbakeji Adari eto aabo lorilẹede Ethiopia ti ni ọgagun to wa ni idi ifipa gba ijọba to waye ni Ethiopia ti sa lọ kuro ni ilu, ti won ko si mọ irin rẹ.

Gedebe Hailu to jẹ Igbakeji adari eto aabo lorilẹede Ethiopia lo sọ bẹẹ fun Ile Isẹ Iroyin BBC, lẹyin ti rogbodiyan sẹlẹ lorilẹede Ethiopia, ti ọpọlọpọ awọn ologun si farapa.

Haliu ni ikọlu naa waye ni awọn ile isẹ ajọ ọlọpaa lorilẹede naa ati olu ile isẹ ẹgbọ oselu (Amhara Democratic Party (ADP) to wa ni ijọba lorilẹede naa.

Asamnew Tsige ni wọn sọ wi pe o se olori akitiyan lati gbe ijọba ologun kalẹ nipa isekupa awọn adari ologun.

Tsige ko ṣẹṣẹ ma gbiyanju lati ditẹgbajọba.O ti ṣaaju gbiyanju ikọlu si ijọba ni ọdun 2008, eleyii ti o si sọ ọ di ero ẹwọn gbere.

Amọ, lẹyin to lo ọdun mẹsan lẹwọn, Olootu Ijọba, Abiy Ahmed tu silẹ ni ọdun to kọja.

Ta ni olori ọmọ ogun Ethiopia, Saere Mekonnen?

Saere Mekonnen ni olori gbogbo ọmọ ogun orilẹ-ede Ethiopia nilẹ Adulawọ.

Oun lo n mojuto idari awọn ọmọ ogun lori eto aabo ẹmi ati dukia awọn eniyan Ethiopia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo ń retí láti ọ̀dọ̀ bàbá mi nígbà tí mo gbọ́ pé ó bá ìjàmbá bàálù lọ

Ogagun agba Saere Mekonnen wa lara awọn ti o di ilu mu ninu iditẹ gbajọba naa to gbẹmi ọpọlọpọ.

O ṣe atunṣe si iṣẹ awọn ọmọ ogun Ethiopia ni eyi to gba pe o maa jẹ ojutu siṣoro to n koju eto aabo wọn

O faragbọta pẹlu awọn ọmọ ogun kan ti wọn si sare gbe lọ sile iwosan fun itọju.

Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ nitori, wọn ti kede pe O ku sinu iditẹ-gbajọba to ṣẹlẹ ni Addis Ababa naa.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán iku ogun lo n pa akikanju bi iku odo ṣe n pa omuwẹ

Awọn wo lo ti ba iṣẹlẹ naa rin?

Olorí ogun Ethiopia ti kú sínú ìdìtẹ̀-gbàjọba Ethiopia

Ileeṣẹ iroyin Ethiopia ti kede pe olori ọmọ ogun ti gbẹmi mi.

Wọn kede pe Saere Mekonnen atawọn olori ikọ ogun mẹrin ti wọn kọkọ faragbọgbẹ ninu iṣẹlẹ naa ti doloogbe.

Bakan naa ni wọn tun kede iku Ambachew Meckonnen to jẹ gomina ẹkun Amhara ati olubadamọran rẹ ti wọn ba iṣẹlẹ iditẹ-gbajọba naa rin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionArákùnrin Ethiopia yìí ń fi ọwọ rin

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin:

Olootu ijọba Ethiopia, Abiy ahmed sọ pe lootọ ni olori ogun orilẹ-ede naa fi ara gba ibọn.

Eyi waye lẹyin ija ajakuakata to waye ni ẹkùn Amhara, to wa ni apa Ariwa orilẹ-ede ọhun.

Abiy tun sọ pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun ni wọn ti ṣekupa ninu ikọlu kan to waye ni olu ilu agbegbe Amhara, Bahir Dar.

Ọgbẹni Abiy sọ pe lasiko ti awọn ọmọ ogun naa n ṣepade lọwọ ni 'awọn akẹgbẹ wọn kan'' kọlu wọn, ti wọn si yinbọn pa wọn.

Iroyin tilẹ sọ pe oju opo ayelujara ti dẹnu kọlẹ ni Ethiopia, ti awọn araalu ni Bahir Dar si n gbọ iro ibọn ni kikan-kikan.

Àkọlé àwòrán Ayelujara ti ẹnu kọlẹ ni Ethiopia

Bakan naa ni ileeṣẹ Amẹrika sọ pe iroyin sọ pe iro ibọn n dun ni olu ilu Ethiopia, Addis Ababa.

Ọdun to kọja ni wọn dibo yan Ọgbẹni AhmedAbiy Ahmed di olóòtú ìjọba Ethiopia, to si ti gbe igbesẹ lati fi opin si ija oṣelu.

O ṣe eyi nipa titu awọn ẹlẹwọn oṣelu silẹ, o si tun pa ofin ti ko faaye gba ṣiṣe ẹgbẹ oṣelu rẹ.

Bakan naa ni Ahmed fi oju awọn alaṣẹ ijọba ti wọn fi ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ wina ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWidows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Ṣugbọn, lati igba ti Ahmed ti de ipo ni ija ẹlẹyamẹya ti pada si Ethiopia,

O to eniyan bi miliọnu meji aabọ ti wọn ti di alainilelori gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ Iṣọkan Agbaye, UN, ṣe sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEbola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀