Lagos building collapse: Àtúnṣe tí kò bófin mu ló fa ilé tó wó lu ènìyàn méjì ní Oshodi - LASEMA

Ile alaja meji to wo ni Oshodi Image copyright lasema
Àkọlé àwòrán Ile naa pa awọn eniyan meji lara

Lọjọ Aiku ni ilé alaja kan wo lu awọn meji nipinlẹ Eko.

Lẹ́yin ti ile alaja kan wo lu eniyan meji ni adugbo Mafoluku ni Oshodi, Ipinlẹ Eko, ni ajọ to n koju isẹlẹ pajawiri ni Ipinlẹ Eko (LASEMA) sọrọ.

Wọn ni ṣe ni awọn to ni ile naa n ṣe atunṣe ti ko bofin mu ko to di pe ile naa wo lulẹ.

Awọn mejeeji to fara kaasa iṣẹlẹ naa wa nile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju.

Adari LASEMA, Oke Osanyintolu to ko awọn oṣiṣẹ pajawiri lọ ibi iṣẹlẹ naa ni wọn n ṣe atunṣe bonkẹlẹ lori ile naa ki ileeṣẹ to n gbogun ti awọn ile àlàpà (LASBCA) ma baa wa wo o ni.

Image copyright LASEMA

Osanyintolu tun ṣalaye wi pe awọn oṣiṣẹ ijọba yoo ṣe ayẹwo ile mejeeji to wa ni ẹgbẹ ile ọhun lati mọ boya awọn naa ti di alapa.

Agbẹnusọ ajọ LASBCA, Titi Ajirotutu ni awọn agbofinro ti fi alabojuto iṣẹ atunṣe ti wọn n ṣe lori ile to wo naa, Dada Olaniyi si ahamọ.

Ajirotutu ni wọn n tun ile naa ṣe ki wọn baa le tete ta a ni.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEbola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀