Ìbéèrè pọ̀ lórí òkú ọkùnrin kan tí ọlọ́pàá bá nínú àgbá ní Oyingbo

Borno Way ati Adugbo Kano ni Ipinlẹ Eko
Àkọlé àwòrán,

Ìbéèrè pọ̀ lórí òkú ọkùnrin kan tí ọlọ́pàá bá nínú àgbá ní Oyingbo

Awọn ara ipinlẹ Eko n fooya lori oku ọkunrin kan.

Ọpọ àwọn olugbe iyana Borno Way ati adugbo Kano ni Yaba nilu Eko ni o n kọminú nípa òkú arakunrin kan ti wọn ba ninu agbá ni adugbo naa ni ọjọ Aiku.

Bi ọpọ awọn aladugbo ṣe n sọ pe o jẹ mọ iṣẹ ọwọ awọn agbenipa to n fi eniyan ṣe oogun owo ni awọn miran ni o ṣeeṣe ko jẹ iṣẹ ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Akọroyin wa kàn si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Bala Elkanah lori ọrọ naa.

O ni iwadii n lọ lọwọ lori ọrọ naa ati pe o ti yaju lati sọ ni pato bi ọkunrin naa ti wọn ba ara rẹ ninu agba naa ṣe ku.

A tun beere lọwọ rẹ boya wọn tilẹ ti mọ ibi ti ọkunrin naa ti wa.

Ṣugbọn O ni rara.

Ọkan lara wọn alaabo ilu to wa ni adugbo naa to mọ nipa ọrọ naa, Ishola Agbodemu ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n ṣoṣẹ ni agbegbe naa lọpọlọpọ.

Àkọlé fídíò,

Ọwọ́ ọlọ́pàá kò tíì tẹ àwọn jàńdùkú tó ṣiṣẹ́ náà

Iroyin ni, ọmọde meji ni o ti sọnu ni agbegbe naa laarin oṣu kan sẹyin.

Agbọdẹmu ni nitori ọrọ aabo to mẹhẹ ni agbegbe naa ni oun ṣe ko igbimọ ẹlẹni ogoji kan jọ lati maa boju to awọn nkan to n lọ ni awọn adugbo.

Ati lati ri wi pe wọn mu awọn janduku to n da ilu ru laipẹ.

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

Agbodemu ni ọwọ awọn ti ba afẹsunkan kan ti orukọ rẹ n jẹ Sola Saliu.

O jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to n gbimọ lati ko awọn janduku wọ adugbo nitori ọmọ ẹgbẹ wọn kan to padanu ẹmi rẹ.

Àwọm ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: