Ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ìdìbò ààrẹ kọ ẹ̀bẹ̀ ẹgbẹ́ PDP láti yẹ ojú òpó ayélujára INEC wò

Atiku Abubakar

Igbimọ to n gbọ ẹsun to su yọ lori eto idibo aarẹ ti kọ ẹbẹ oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, lati ṣayẹwo oju opo ayelujara ajọ INEC eyi ti wọn pe ni "Server".

Awọn ọmọ igbimọ maraarun naa fi ẹnu ko lori igbesẹ ọhun lati ma fi aaye gba ẹgbẹ oṣelu PDP ati oludije rẹ, Atiku Abubakar, nitori awọn nkan mii to tun ti kún ẹjọ naa nipa oju opo ayelujara INEC.

Awọn adajọ naa sọ pe nibi ti nkan de bayii, igbimọ ọhun ko tun le ti ọwọ bọ wahala boya INEC lo ẹrọ ayelujara lati ṣafihan esi idibo tabi ko lo o.

Ọnidajọ Garba to ka idajọ naa sita sọ pe ṣiṣe bẹ 'ko mu ọgbọn dani''.

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

O ni ti ile ẹjọ ba fi aaye gba ẹgbẹ PDP, eyi tumọ si pe 'wọn ti gba pe oju opo ayelujara apapọ kan wa ti gbogbo esi idibo ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji wa.''