EFCC: Ẹlẹ́rìí ṣàlàyé bí wọ́n ti ṣé gbé N1.2bn fún Obanikoro

Aworan Obanikoro
Àkọlé àwòrán,

EFCC: Ẹlẹ́rìí ṣàlàyé bí wọ́n ti ṣé gbé N1.2bn fún Obanikoro

Apo nla marunlelọgọta la fi gbe owo wa fun Obanikoro nigba naa.

Ẹlẹri kan ti salaye fadajọ to n gbọ ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan Minisita eto aabo tẹlẹri ni Naijiria,Musiliu Obanikoro, bi oun ti ṣe gbe owo to le ni biliọnu naira fun un.

Lasiko igbẹjọ to waye kẹyin niwaju adajọ Nnamdi Dimgba ti ile ẹjọ giga ni ilu Abuja lo ti tu pẹpẹ ọrọ yi.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra fi sita ṣalaye EFCC fidiẹ mulẹ ni.

Atẹjade ti wọn fi sita naa ni Abiodun Agbele to fi'gba kan jẹ isọmọgbe gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti salaye bi oun ti ṣe ṣeto gbigbe owo fun Obanikoro.

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

O ni owo ọhun le ni biliọnu naira ki Fayose le wọle lasiko idibo gomina Ekiti lọdun 2014.

Ẹkunrẹrẹ alaye nipa bi wọn ti ṣe gbe owo naa lati papakọ ofurufu ilu Eko ti wọn si gbe e fun Obanikoro ni eleri miran Damola Otuyalo ṣe fun ile ẹjọ.

Àkọlé àwòrán,

O ti to ọjọ mẹta ti igbẹjọ ẹsun jẹgudujẹra ti wọn fi kan Musiliu Obanikoro ti n waye

Otuyalo ti o jẹ adari awọn oṣiṣe eto gbigbe owo to pọ nigba kan ri nile ifowopamọ Diamond Bank ni apo nla marundinlaadọrin lawọn fi gbe owo naa.

O ni owó ọhun ni ọga oun si paṣẹ foun lori ẹrọ ibanisọrọ lati gbe fun Musiliu Obanikoro.

Ẹjọ owo yi nii ṣe pẹlu owo ti ijọba ni gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose gba lọwọ oludamọran lori ọrọ aabo fun aarẹ tẹlẹri Dasuki Sambo.

Owo naa lapapọ le ni biliọnu mẹrin naira.

Lẹyin ti awọn eleri wi tẹnu wọn ti wọn si fi iwe jẹri si ọrọ ti wọn sọ, adajọ Dimgba sun igbejọ naa siwaju titi di ọjọ kẹrin oṣu Kẹwa ọdun 2019.

Àkọlé fídíò,

Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó