Ìgbà mélòó ní wọn fẹ kéde ikú ẹṣọ tó pá Ọ̀gágun Lorílè-èdè Ethiopia ?

AWORAN ỌGAGUN TI WỌN PA
Àkọlé àwòrán,

Ẹ̀ṣọ́ tó pa Ọ̀gágun Ethiopia tí a sọ pé ó kú, kò kú mọ́! -Ọlọ́pàá

Ẹ fori jin wa, ẹni ta a lo ku tẹlẹ, ko ku mọ.

Ikede yi lo waye lati ẹnu ileeṣẹ ọlọpaa apapọ lorile-ede Ethiopia ti o kọkọ sọ pe ẹṣọ to ṣekupa olori ọmọ ọgun ilẹ naa Ọgagun, Seare Mekonnen, ti yinbọn pa ara rẹ.

Ni bayi ohun ti wọn n sọ ni pe ẹṣọ naa ko ku mọ ati pe o n gba itọju lọwọ nile iwosan ni.

Ile iṣẹ olootu ijọba ilẹ naa sọ pe ẹsọ naa lo ṣeku pa ọgagun naa pẹlu ọga ọmọ ogun mii, ọgagun Gezai Abera ninu igbiyanju ati fitẹgbajọba.

Eyi ni igba ẹlẹẹkeji ti iroyin yoo ma yipada nipa ohun to ṣẹlẹ si ẹṣọ yi.

Àkọlé fídíò,

Mo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Ni ọjọ Ẹti, ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa kọkọ kede ni pe ọwọ ti tẹ ẹsọ naa, lẹyin igba naa ni wọn ni o yinbọn pa ara rẹ lẹyin to ṣeku pa awọn ọgagun mejeeji.

Ko ti si aridaju boya ẹsọ naa n gba itọju fun ọgbẹ ti o fi ọwọ ara rẹ da tabi eleyi ti wọn da si lara.

Àkọlé fídíò,

Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè